Wo ohun tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó ní INEC dá orúkọ ẹgbẹ́ márùn-ún padà túmọ̀ sí fún Adeleke, Oriyomi

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu Accord Party ti kan saara si idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun lori bo ṣe da idajọ ile ejọ to ga ti ijọba apapọ to ni ki ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu marun-un kuro ninu akọọlẹ rẹ.
Ẹgbẹ oṣelu Accord juwe idajọ naa bi imuduro iṣejọba awaarawa, idajọ ododo ati ṣiṣe ohun to tọ pẹlu ilana to yẹ.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Maxwell Mgbudem fi lede lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Keje lẹyin ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe idajọ naa ti mu ki awọn eeyan maa ni igboya ninu ẹka eto idajọ Naijiria.
O woye pe idajọ naa jẹ aroko pe iṣejọba awaarawa ni Naijiria le koju erongba lati yi iwe ofin pada lori iduroire iṣejọba awaarawa.
O ni idajọ naa ti ṣe afọmọ si awọn ifanfa to n waye lagbo oṣelu Naijiria, to si jẹ atọna pe awọn eeyan ṣi le ni igboya ninu ẹka eto idajọ gẹgẹ bi ibi ti awọn eeyan ti le ri idajọ ododo gba.
Mgbudem ni ṣaaju ki ile ẹjọ giga to gbe idajọ rẹ kalẹ ni ẹgbẹ naa ti pe ẹjọ Kotẹmilọrun, to si dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun bibu ẹnu atẹ lu idajọ ile ẹjọ giga naa, to si jẹjẹẹ lati maa mu igbega ba iṣejọba awaarawa ni Naijiria.
Atiku sọrọ lori idajọ naa
Bakan naa ni oludije lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, Atiku Abubakar naa ti gboriyin fun idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun naa.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ Atiku fi lede juwe idajọ naa bii igboya, ifarajin si ootọ ati mimu idajọ ododo wa si imuṣẹ.
Atiku ni bi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 ṣe n sunmọ etile, o ni o yẹ ki idije oṣelu jẹ ohun ti awọn eeyan maa pinnu funra wọn pẹlu idibo dipo lilo ile ẹjọ lati fi bori ohun to yẹ ko jẹ pe ibudo idibo ni wọn ti maa bori rẹ.
O fi kun pe idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun naa ati idajọ ile ẹjọ giga ilu Abuja kan to fidi igun Sẹnetọ David Mark mulẹ gẹge bi alaṣẹ ẹgbẹ naa ti fopin si gbogbo awọn igbẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu naa n koju ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
O tẹsiwaju pe eyi ti fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu naa ti ni anfaani lati kopa nibi eto idibo ọdun 2027.
Ki ni idajọ naa tumọ si fun Adeleke, Oriyomi atawọn mii?
Ohun ti idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun yii tumọ si ni pe gbogbo awọn oludije labẹ awọn ẹgbẹ oṣelu marun-un ti ile ẹjọ giga ti ni ki INEC wọgile orukọ wọn ni yoo le kopa nibi eto idibo to n bọ.
Eyi tumọ si pe Ademola Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu Accord yoo le kopa nibi eto idibo sipo gomina ti yoo waye lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ.
Bakan naa ni Oriyomi Hamzat yoo ni anfaani lati kopa nibi eto idibo sipo gomina ipinlẹ Osun nibi eto idibo gbogbogbo to n bọ.
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìdájọ́ tó pàṣẹ kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ Atiku kúrò nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ kọtẹmilọrun ilu Abuja ti wọgile idajọ to paṣẹ fun ajọ INEC lati fa orukọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ati ẹgbẹ oṣelu mẹrin mii yọ ninu akọsilẹ rẹ lori pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ko ni awọn amuyẹ to to.
Ninu idajọ igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ti wọn gbe idajọ naa kalẹ, wọn ni idajọ ti ile ẹjó giga gbe kalẹ ṣaaju ko lẹsẹ nilẹ.
Gẹgẹ bii ile ẹjọ ọhun ṣe sọ, ko si igbẹjọ kankan niwaju ile ẹjọ giga naa to fi yẹ ko paṣẹ fun INEC pe ko yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ninu akọsilẹ rẹ.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa tun ṣalaye pe ile ẹjọ naa kuna lati yẹ gbogbo awọn ẹri to wa niwaju rẹ wo nitori o kuna lati naani awọn ẹri to fi han pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ti jawe olubori ninu awọn eto idibo kan.
O sọ siwaju pe ile ẹjọ giga naa tun kọ eti ọgbọin si aṣẹ to ti waye ṣaaju wi pe ko ma da si ọrọ ọhun rara.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ni niṣe lo yẹ ki ile ẹjọ giga naa da ẹjọ ọhun nu larari pe ko lẹsẹ nilẹ ati pe ko lagbara lati gbọ ẹjọ naa.
Idajọ tuntun yii lo n waye lẹyin ti awọn ẹgbẹ oṣelu ti ọrọ kan gbe ọrọ naa wa siwaju rẹ.
Lẹyin naa lo sọ pe ki ajọ to pe ẹjọ naa ṣaaju, National Forum of Former Legislators (NFFL), san owo fun awọn ẹgbẹ oṣelu naa.
Yatọ si ADC, awọn ẹgbẹ oṣelu mii ti ọrọ naa kan ni Action Peoples Party (APP), Action Alliance (AA), Accord Party (AP), ati Zenith Labour Party (ZLP).
Ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Atiku, Oriyomi àti ẹgbẹ́ mẹ́ta mii kúrò nínú àkọsílẹ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú
Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord ati ẹgbẹ oṣelu mẹta mii kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo 2027 to n bọ.
Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta toku ni ẹgbẹ APP, ẹgbẹ oṣelu AA, ati ẹgbẹ ZLP.
Adajọ Peter Lifu lo paṣẹ naa nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.
Ṣaaju ni igbimọ awọn aṣofin tẹlẹri ti beere pe ki ile ẹjọ sọ boya ajọ eleto idibo INEC lagbara labẹ ofin lati yọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati ṣe nnkan ti abala 225A iwe ofin orilẹede Naijiria sọ kuro, eyi to wa ni ibamu pẹlu atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2022.
Igbimo awọn aṣofin tẹlẹri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un yii ti kuna lati maa tẹsiwaju gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.
Lara awọn nnkan amuyẹ tawọn aṣofin naa sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa kuna lati ni, ni ida 25% ibo nipinlẹ kan lasiko eto idibo aarẹ to kọja.
Amuyẹ mii ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu yii gbọdọ ni aṣoju kan ti araalu dibo yan yala ni ijọba ibilẹ tabi ipinlẹ tabi nile aṣofin agba l'Abuja.
Awọn olupẹjọ naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin yoku fidirẹmi ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023 ati ninu atundi ibo to waye debi wi pe wọn ko ni aṣoju kankan ti araalu dibo yan.
Awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii ṣe wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu eto idibo to n bọ lodi sofin orilẹede Naijiria ati ofin eto idibo.
Lẹyin naa ni wọn rọ ile ẹjọ pe ki o yọ orukọ awọn ẹgbẹ marun un naa kuro ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Bakan naa tun ni awọn olupẹjọ tun rọ ile ẹjọ lati fofin de awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ipolongo ibo ati eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Wọn tun rọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ fun ajọ INEC pe ko gbọdọ ni ibaṣepọ kankan pelu awọn ẹgbẹ naa mọ.
Idajọ yii yoo ṣakoba fun Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, to fẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC ninu eto idibo ọdun 2027.



























