Àlàyé lórí bí Tinubu ṣe fi ìwé ẹ̀rí fásítì rẹ̀ nìkan ṣọwọ́ sí INEC tó sì kùnà láti fi ìwé ẹ̀rí alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ránṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook
Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC fi gbe fọọmu ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu buwọ lu lati fi dije du ipo aarẹ lẹẹkeji sita fun gbogbo araalu.
Ninu fọọmu naa ni Aarẹ Tinubu ti kọ lati fi orukọ awọn ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama sibẹ, ti ko si jẹ kẹnikẹni mọ ibi to ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ lati kekere.
Imọ ẹkọ to ni ni fasiti nikan ni Aarẹ Tinubu fi sinu fọọmu naa, eyi to loun gba lọdun 1979, ti ko si fi orukọ fasiti ọhun sita.
Fasiti ipinlẹ Chicago to wa nilẹ Amẹrika ni Tinubu ti kẹkọọgboye BSc ni ẹka abojuto okoowo lọdun 1979.
Ni agbegbe ti wọn sọ ya sọtọ lati fi orukọ ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama si, aarẹ ko kọ ohunkohun sibẹ, ko to da a pada fun ajọ eleto idibo.
Ṣugbọn ṣa, Aarẹ Tinubu fi iwe ẹri to gba ni fasiti naa, ati iwe ẹri ṣiṣe agunbanirọ si ẹyin fọọmu ọhun, lati fi gbe e lẹyin.
Bakan naa, Tinubu jẹ ko di mimọ pe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 1952 ni wọn bi oun siluu Eko, to si ṣalaye pe iṣẹ oloṣelu loun yan laayo.
Nigba to n tọka si awọn ibi to ti ṣiṣẹ, Aarẹ sọ pe oun ṣiṣẹ nileese Mobil Nigeria Limited laaarin ọdun 1983 ati 1992, ko to di pe o di gomina ipinlẹ Eko fun igba meji ọtọọtọ, iyẹn laaarin ọdun 1999 si 2007.
O ni abẹ ijọba apapọ loun ti n ṣiṣẹ lọwọlọwọ, toun si bẹrẹ lọdun 2023 titi di asiko yii, ati pe wọn ko tii figba kankan le oun danu lẹnu iṣẹ ijọba ri.
Gbigbe awọn iwe yii sita lo jẹ ibẹrẹpẹpẹ awọn ayẹwo ati awọn iwe ẹri ti gbogbo awọn oludije kọọkan, lati jẹ ki awọn araalu foju ri i.
Ki ni iwe ofin sọ nipa iwe ẹri oludije?
Ni abala kẹtalelọgbọn ninu iwe ofin eto idibo nilẹ Naijiria, o sọ pe ẹnikẹni to ba gbagbọ pe ayederu ni awọn iwe ẹri ti oludije kan ba fi ranṣẹ si ajọ eleto idibo, le pe ẹjọ lati tako o, pẹlu awọn ẹri to jọju.
Ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ ni ajọ INEC sọ pe awọn yoo fi awọn iwe ẹri oludije sita fun gbogbo aye lati ri.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2027 ni eto idibo aarẹ yoo waye nilẹ Naijiria, bo tilẹ jẹ pe oṣu yii ni eto ipolongo yoo bẹrẹ kaakiri.





























