'Adeleke kọ́ ló máa sọ ẹni táwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun máa dìbò fún, kìí olórí ẹgbẹ́ Accord'

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oludije sipo aarẹ Naijiria lẹgbe oṣelu Accord Party, Gbenga Olawepo-Hashim ti ni bi gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ṣe fontẹ lu Aarẹ Bola Ahmed ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ko tumọ si pe awọn eeyan ipinlẹ naa maa dibo fun Tinubu.
Olawepo-Hashim lo n sọ eyi lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC fi orukọ Gomina Adeleke sara awọn to maa ṣe ipolngo ibo fun atunyansipo Aarẹ Bola Tinubu nibi eto idibo ọdun 2027.
O nib o ṣe jẹ pe Adeleke nikan ni gomina ti ẹgbẹ oṣelu Accord ni ko tumọ si pe o ti di olori ẹgbẹ naa, to si ni awọn igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ nikan lo lẹtọọ lati dari awọn ọmọ ẹgbẹ lati dibo si ibi ti wọn ba fẹ.
Ẹ o ranti pe lẹyin Gomina Adeleke wọle ibo fun saa keji ninu oṣu Kẹjọ lo kede atilẹyin rẹ fun Tinubu amọ ti Olawepo-Hashim n sọ bayii pe oun kọ lo maa yan le awọn eeyan ipinlẹ lọwọ.
O ni oun nigbagbọ pe Ọmọluabi ni awọn eeyan ipinlẹ Osun, to si jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Accord ni wọn maa dibo fun ti asiko ibo ba to lai fo ti gomina Adeleke ṣe.
O fi kun pe ọpọ ọmọ Naijiria lo ti pinnu pe awọn ko ni dibo fun egbe oṣelu APC ati Tinubu nibi eto idibo ọdun 2027.
O fẹsun kan pe ijọba ti Tinubu n dari ko ṣe amojuto eto ọrọ aje daadaa, ti eto aabo labẹ iṣejọba to wa lode tun ti buru sii, to si tun ni ijọba ko naani igbayegbadun awọn araalu.
O tẹmpẹlẹmọ pe iṣẹ ti oloṣelu kọọkan ba ṣe lo maa sọ bi awọn eeyan ṣe maa dibo fun wọn dipo didibo fun orukọ.
APC yan Adeleke, Wike, Soludo àtàwọn míì láti mójútó ìpolongo wíwọlé Tinubu fún sáà kejì

Oríṣun àwòrán, @others
Egbe oṣelu All Progressive Congress (APC) ti kede orukọ awọn ti yoo wa ninu ipolongo eto idibo to m bọ ti yoo ri si bi Aarẹ Bola Tinubu yoo ṣe wọle saa keji gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lẹẹkan sii.
Lara awọn ti wọn yan ni Gomina ipinlẹ Osun labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord PArty, Ademola Adeleke, Minista fun olu ilu Naijiria ni Abuja, FCT, Nyesom Wike ati Gomina Soludo.
Iṣe ti wọn yan fun onikaluku ṣotọọtọ ki wọn ṣa ti ṣiṣẹ papọ rii pe Aarẹ Tinubu lo gbegba oroke ninu eto idibo to m bọ ni.
Iṣẹ Adeleke ni lati rii pe awọn eniyan ipinlẹ Osun dibo yan Aarẹ Tinubu pada.
Ọla Ọjọ Ru, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaaa, ọdun 2026 ni wọn yoo ṣe ifilọle awọn olupolongo naa ni gbọgan Banqueth Hall nile Ijoba ni Aso Rock nilu Abuja.
Awon mii wo lo tun wa nibẹ?
Awọn miran ti won yan lati rii pe Aarẹ Tinubu tun wọle ni 2027 ni:-
-Gomina ipinlẹ Delta, Sherrif Oborevwori gẹgẹ bii oludari eto inawo ipolongo naa.
-Gomina Dapo Abiodun to n tukọ ipinlẹ Ogun ati alaga Nigeria Revenue Service to n ri si bi owo ṣe n wọle ni NAijiria, Zacch Adedeji ni yoo ri si bi wọn yoo ṣe ri owo na fun ipolongo naa.
-Benjamin Kalu to jẹ igbakeji Abẹnugan ile igbimọ Assofin kekere ni Abuja ni yoo jẹ igbakeji oludari ipolongo ẹka South South 11.
-David Umahi to jẹ minista ọrọ iṣe akanṣe fun NAijria ni wọn yan gẹgẹ bii igabkeji adari ohun amayedẹrun.
Awọn miran to tun wa nibẹ ni:-
-Martin Amaewhule to jẹ Abenugan ile igbimo aṣofin ipinle Rivers.
-Abdullahi Ganduje to jẹ gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ.
-Babatunde Raji Faṣola to jẹ gomina ipinlẹ Eko nigab kan ri
























