Wo gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa WAFCON 2026

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Idije Ife ẹyẹ awọn obinrin agbabọọlu ilẹ Africa ti a mọ si Africa Cup of Nations (WAFCON), to pẹ diẹ ni 2026 yii ti pada ṣetan lati gberasọ.
Orilẹede Morocco lo si fẹ gba alejo rẹ fun igba kẹta ni tẹle-n-tẹle.
Tẹlẹ, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta si ọjọ kẹta oṣu Kẹrin ni wọn fi WAFCON ọdun yii si pe yoo waye, amọ ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba nilẹ Africa; 'Confederation of African Football (CAF), sun un siwaju nigba to ku ọjọ mejila ti yoo bẹrẹ.
WAFCON ọdun yii to n waye lẹyin ọdun kan iru rẹ to ṣẹlẹ ni 2024, yoo bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2026, nigba ti ikọ agbabọọlu Algeria yoo maa koju Senegal ninu ayo ti yoo ṣide idije naa ni Rabat.
Aago marun-un irọlẹ ni yoo maa waye.
Gẹgẹ bi CAF ṣe fojusun awọn kudiẹ-kudiẹ kan ṣaaju, to mu ki asiko ti idije naa yoo bẹrẹ sun siwaju, o pada fun wọn ni anfaani asiko to pọ si i fun ikọ ẹlẹni mẹrindinlogun naa.
Ifẹsẹwọnsẹ mẹrinlelọgbọn ni yoo waye ninu rẹ lapapọ, ti yoo si pari si ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ.
Idije WAFCON ọdun yii ṣe pataki nitori o tun jẹ jẹ atọna fun idije ife ẹyẹ awọn agbabọọlu obinrin lagbaaye, iyẹn 2027 Fifa Women's World Cup.
Ninu rẹ ni awọn ikọ mẹrin to ba de ipele to kan ṣaaju aṣekagba yoo ti gba tikẹẹti ti yoo gbe wọn lọ si Brazil.
Eyi ni bi gbogbo ẹ yoo ṣe lọ ninu idije yii, bi BBC ṣe mu wọn wa nipele-ipele.
Awọn ikọ wo lo wa?
Ikọ agbabọọlu mẹrindinlogun ni wọn ti pin si isọri mẹrin-mẹrin.
Morocco to n gbalejo yoo koju Algeria nipele A, bẹẹ ni yoo koju Senegal ati Kenya.
Group A: Morocco, Algeria, Senegal, Kenya.
Group B: South Africa, Ivory Coast, Burkina Faso, Tanzania.
Group C: Nigeria (holders), Zambia, Egypt, Malawi.
Group D: Ghana, Cameroon, Mali, Cape Verde.
Awọn asiko ti yoo bẹrẹ
Aago marun-un irọlẹ ati aago mẹjọ alẹ ni awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo maa waye ti wọn yoo fi pari rẹ, afi aṣekagba nikan ni yoo yatọ.
Ipele ko mẹsẹ o yọ eleni mẹjọ ( Quarter-finals) yoo waye lọjọ kẹjọ si ikẹsan-an oṣu Kẹjọ, nigba ti ipele to kangun si aṣekagba (Semi-finals) yoo maa waye lọjọ kejila oṣu Kẹjọ.
Aṣekagba idije naa yoo waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026, ni aago meje alẹ.
Nibo ni wọn yoo ti maa gba WAFCON 2026 ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Morocco lo papa iṣere mẹfa to wa ni ilu marun-un lọdun to kọja, amọ bii marun-un ni wọn fẹ lo ni ilu meji lọdun yii.
Ibi marun-un ti wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn yoo ti gba WAFCON 2026 ni Morocco ni:
- Moulay Hassan Stadium, Rabat
- Olympic Stadium, Rabat
- Al Medina Stadium, Rabat
- Larbi Zaouli Stadium, Casablanca
- Moulay Rachid Stadium, Casablanca
Awọn wo ni ààyò?

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Ninu orilẹede mẹrindinlogun to n kopa, Naijiria ati South Africa nikan ni won ti gba ami ẹyẹ yii ri
Ikọ Super Falcons Naijiria gba iyi gẹgẹ bii ẹni to gbe ife ẹyẹ naa dani lọwọlọwọ yii, labẹ idari Akọnimọọgba wọn, Justin Madugu.
Chiamaka Nnadozie ni wọn pe ni amule to daa julọ nilẹ Africa, lati ọdun mẹta sẹyin, nigba ti Balogun ikọ naa, Rasheedat Ajibade, gba orukọ agbabọọlu to wuyi julọ laṣekagba idije naa to waye loṣu Keje ọdun to kọja.
Morocco nawo ribiribi si idije bọọlu lẹnu ọdun diẹ si asiko yii, amọ awọn ikọ agbabọọlu obinrin rẹ ko ti i rọwọ yọ bii awọn ọkunrin wọn.
South Africa, ni wọn ka si ipo keji, Desiree Ellis ṣi n ṣe daadaa fun wọn, nigba ti Ghana, wa nipo kẹta labẹ Kim Bjorkegren.
Zambia lo kangun awọn ikọ to lẹnu yii, bo tilẹ jẹ pe awọn Copper Queens rẹ gba odo marun-un ti Naijiria ko le wọn lọwọ nipele ko mẹsẹ o yọ lọdun to kọja.
Awọn naa yoo fọkan tan elegeara wọn, Barbra Banda, to gba agbabọọlu obinrin to daa ju ni 2024 fun aṣeyọri.
Bi wọn ṣe to o

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje
Isọri A: Algeria v Senegal, Olympic Stadium, Rabat, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri A: Morocco v Kenya, Moulay Hassan Stadium, Rabat, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keje
Isọri B: South Africa v Tanzania, Moulay Rachid Stadium, Casablanca, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri B: Ivory Coast v Burkina Faso, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keje
Isọri C: Zambia v Egypt, Olympic Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri C: Nigeria v Malawi, Al Medina Stadium, Rabat, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọru, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Keje
Isọri D: Ghana v Cape Verde, Moulay Rachid Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri D: Cameroon vs Mali, Larbi Zaouli Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọbọ, ọgbọnjọ oṣu Keje
Isọri A: Senegal v Kenya, Olympic Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri A: Morocco v Algeria, Moulay Hassan Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keja
Isọri B: South Africa v Ivory Coast, Moulay Rachid Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri B: Burkina Faso v Tanzania, Larbi Zaouli Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Satide, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹjọ
Isọri C: Egypt v Malawi, Moulay Hassan Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọri C: Nigeria v Zambia, Al Medina Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Aiku ọjọ keji oṣu Kẹjọ
Isọri D: Ghana v Cameroon, Moulay Rachid Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
Isọro D: Mali v Cape Verde, Larbi Zaouli Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu Kẹjọ
Isọri A: Senegal v Morocco, Moulay Hassan Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Isọri A: Kenya v Algeria, Olympic Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ
Isọri B: Burkina Faso v South Africa, Moulay Rachid Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Isọri B: Tanzania v Ivory Coast, Larbi Zaouli Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Kẹjọ
Isọri C: Egypt v Nigeria, Olympic Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Isọri C: Malawi v Zambia, Al Medina Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ọjọbọ, ọjọ kẹfa oṣu Kẹjọ
Isọri D: Mali v Ghana, Moulay Rachid Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Isọri D: Cape Verde v Cameroon, Larbi Zaouli Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ìpele ko mẹsẹ o yọ eleni mẹjọ WAFCON 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Satide ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ
QF 2: ipele awọn to ba jawe olubori ni isọri B ati tawọn to ba ṣepo keji ni isọri A Rachid Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
QF 1: Awon to jawe olubori nisọri A yoo koju awọn to ba ṣepo keji nisọri B Moulay Hassan Stadium, (Aago mẹjọ alẹ.)
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹjọ
QF 4: Awọn to jawe olubori ni isọri D yoo koju awọn to ṣepo keji nisọri C, Larbi Zaouli Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
QF 3: Awọn to jawe olubori ni isọri C yoo koju awọn to ṣepo keji nisọri D, Al Medina Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ipele ko mẹsẹ o yọ

Oríṣun àwòrán, Confederation of African Football
Ọjọru,ọjọ kejila oṣu Kẹjọ
SF2: Awọn to ba jawe olubori nipele ko mẹsẹ ọ yọ keji yoo koju awọn to bori niple kẹta, Olympic Stadium, (Aago marun-un irọlẹ)
SF1: Awọn to jawe olubori nipele ko mẹsẹ o yọ akọkọ yoo koju awọn ti iple kẹrin, Moulay Hassan Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Ifẹsẹwọnsẹ lati pegede
Ọjọbọ, ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ
Awọn to ba fẹyin nalẹ nipele ko mẹsẹ o yọ keji yoo koju awọn ti ikẹta, Larbi Zaouli Stadium, Aago marun-un irọlẹ ni yoo waye.
Awọn to padanu nipele ko mẹsẹ o yọ akọkọ yoo koju tawọn ti ikẹrin, Moulay Rachid Stadium, (Aago mẹjọ alẹ)
Aṣekagba WAFCON 2026

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ
Ikọ to bori nipele to kangun si aṣekagba akọkọ yoo koju ikeji, Moulay Hassan Stadium tabi papa iṣere Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat, ni yoo ti waye ni aago meje alẹ.


























