Ẹgbẹ́ tó ń ṣàtìlẹyìn fún Makinde sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook Sunday Igboho/Others
Ẹgbẹ alatilẹyin oṣelu fun Gomina Seyi Makinde ti ṣapejuwe olori ajijangbara fun ominira ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo gẹgẹ bi tọọgi ẹyin oloṣelu ti ko lẹkọọ.
Ẹgbẹ naa ti wọn pe ara wọn ni GSM Advocates sọ pe Igboho ko mọ ohunkohun, bi ko ṣe niṣe lo lo anfaani oṣelu kekere to ri lati maa fi huwa.
Atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita jẹ ko di mimọ pe ọrọ ti Adeyemo tọpọ tun mọ si Igboho sọ si Gomina Seyi Makinde jẹ eyi to tabuku ba ipo ti gomina wa.
Kí ló dé ti Sunday Igboho tún gbéná wojú Gómìnà Makinde ti ìpínlẹ̀ Oyo?
Ẹgbẹ naa sọ pe ohun to ṣeni laanu ni pe iru eeyan bii Sunday Igboho ti ko ni ẹkọ iwe kankan, ti ko si ni akọsilẹ ibi to ti ṣiṣẹ, ti ko tun ni oye nipa ijọba le la ẹnu rẹ lati ṣe ikọlu si gomina to n ṣiṣẹ takuntakun.
Wọn wa jẹ ko di mimọ pe Igboho ti wa wọ ara rẹ nilẹ lati jẹ janduku lẹyin oloṣelu, to si n fo kaakiri ẹyin oloṣelu kan si ekeji lati wa ọna atijẹ.
Siwaju sii ni wọn sọ pe ọrọ awuyewuye ni ọkunrin naa maa n wa lati fi gbajumọ laaarin ilu, ko le fa oju awọn eeyan mọra.
"Janduku lẹyin oloṣelu ni Sunday Igboho jẹ, alailẹkọọ to n wa anfaani oṣelu kekere lati jẹ. O jẹ ọkunrin ti ko ni ile keji, ko si iṣẹ kan ti wọn mọ mọ-ọn, yatọ si pe ko pariwo, ko si da rukerudo silẹ.
"Ko yẹ lẹni to n darukọ Gomina Seyi Makinde nibi apejọ ita gbangba," ẹgbẹ naa sọ bẹẹ.
Siwaju sii ni wọn fi kun atẹjade naa pe Gomina Makinde ti gbe ipo iṣejọba leke kọja ki oloṣelu maa ko tọọgi kaakiri tabi ijangbara iru eyi ti Igboho duro fun.
Wọn fi kun ọrọ wọn pe Makinde ti mu ayipada ọtun ba ipinlẹ Oyo nipa awọn akanṣe iṣẹ lẹka eto ẹkọ, ilera, eto aabo, opopona, iṣẹ agbẹ, to fi mọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ijọba.
Bẹẹ ni wọn fidi rẹ mulẹ pe digbi lawọn araalu wa lẹyin Gomina Makinde, ti wọn si rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba awọn ọrọ Sunday Igboho rara, nitori pe ariwo ọmọ ẹyin oloṣelu lasan to n fẹ ki aye sọrọ rẹ ni.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Screenshot / Seyi Makinde/Facebook
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ ija oṣelu to wa laaarin olori ajijangbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Adeniyi Adeyemo ati Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo yoo yọri si.
Lati bi ọjọ meloo sẹyin la gbọ pe Adeniyi tọpọ mọ si Sunday Igboho ti n tako Gomina Makinde, lori gbogbo igbesẹ to n gbe.
Lọsẹ to kọja ni Igboho sọ pe Gomina Makinde ko ni aṣẹ lati rọ Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja nipo, ti ọrọ naa ko si tii tan nilẹ.
Igboho lo sọrọ naa ninu fọnran kan to n kaakiri ori ayelujara lopin ọẹ to kọja yii, to si ti n fa oniruuru ibeere.
Eyi ni awọn eeyan ṣi n jẹ lẹnu lọwọ, ti Igboho tun jade lati tako Makinde lori ọrọ to sọ nipa Tinubu.
Igboho sọrọ yii nibi eto ifilọlẹ ileeṣẹ alaabo rẹ to pe ni Iru Ekun, eyi to da silẹ lati fi gbogun ti iṣoro to n koju eto aabo lawọn inu igbo kaakiri ẹkun Guusu-Iwọ Oorun Naijiria.
Nigba to n sọrọ, o ni ohun ti bai wa ọmọluabi ni iwa ti Makinde hu laipẹ yii, nibi to ti n fi Aarẹ Tinubu ṣẹlẹya.
O ni oun ko le laju silẹ lati jẹ ki ẹnikẹni tako tabi sọrọ abuku si Aarẹ Tinubu, ati pe ẹni to ba ṣe bẹẹ yoo ri pipọn oju oun.
Ninu ọrọ rẹ, Igboho sọ pe, "O wa n fo soke bi ọpọlọ, o wa ni ṣe Baba Tinubu le fo bayii? Ṣe ẹ rii pe ko ni baba nile? Ọlọrun a jẹ ki ẹmi Baba Tinubu gun daadaa.
"Ki Ọlọrun jẹ ki awa naa dagba to Baba Tinubu. Ki Ọlọrun fun awa naa ni ọmọ ti yoo di Aarẹ Naijiria. Gbogbo ẹnikẹni to ba fẹẹ dagba ko nii fi agba ṣe yẹyẹ.
"Agba wo wa ni Baba Tinubu tii da, ti a n bu? Aarẹ ilẹ Zambia ti fẹẹ to ọdun mọkalelọgọrun kan. Meloo wa lọjọ ori baba ti ẹ n bẹ soke, ti ṣe ẹ sọ pe baba ko le bẹ bẹẹ?
"Ẹni abuku ni yin, ki Ọlọrun ma kan wa labuku. Bi eeyan ba ṣeni loore, ọpẹ la maa da. Baba ṣe mi loore. Gbogbo ẹni to ba ti n bu Tinubu, emi lo n bu.
"Ma maa bu iru ẹni bẹẹ. Ẹni to ba n sọ pe ti Tinubu bawo, ẹmi naa yoo yẹpẹrẹ iru ẹni bẹẹ debi ti ko lero. Iwọ ti o ba ti bu Tinubu, maa fi ẹnu mi yẹpẹrẹ rẹ debi wi pe aye yoo su ọ" Igboho sọ bẹẹ.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Nibi ipolongo kan ti Gomina Seyi Makinde ṣe laipẹ, lo ti n sọ pe ẹni to ba ṣi ni okun ati agbara ni ki awọn eeyan dibo fun lati dari wọn, kii ṣe agbalagba ti ọjọ ti n lọ lori rẹ.
Makinde, ninu fọnran to n kaakiri ori ayelujara sọ pe ki awọn eeyan dibo fun ẹni to ba le fo bii toun lati ori oke bọ si isalẹ.
Fọnran naa to tẹ BBC lọwọ, la ti ri Makinde to fo bọ silẹ lati ori pepele to ti n polongo ibo lọwọ, to si ni bi oludije yooku ba le ṣe iru rẹ, ki awọn eeyan dibo fun wọn.
Ninu ọrọ Makinde, o sọ pe, " Nigba ti wọn ba mu oludije sipo Aarẹ wọn wa, ẹ jẹ ki oludije naa wa sibi, ko si fo bọ silẹ. Bi wọn ba ti le ṣe bẹẹ, ẹ dibo fun wọn."
Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu Makinde, bẹẹ lawọn miran n ṣatilẹyin fun.
Wàhálà yóò ṣẹlẹ̀ bí Gómìná kankan bá rọ Olubadan lóyè - Sunday Igboho fọnmú

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Olori ẹgbẹ ajijangbara nilẹ Yoruba, Sunday Adeniyi Adeyemo ti ṣe ikilọ fun Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo lati dẹkun erongba yiyọ Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Ladoja n'ipo.
Sunday Adeyemo, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho sọ pe bi gomina kan gbiyanju lati yọ Olubadan nipo, wahala yoo ṣẹlẹ nipinlẹ naa.
Igboho sọ pe digbi loun duro lẹyin Ọba Olubadan, toun si ṣetan lati gbeja rẹ, nigbakugba ti wahala kankan ba fẹẹ dide sii.
Ninu fọnran kan to n kaakiri ayelujara, Igboho sọ pe, bi Makinde ba fi gbe igbesẹ yiyọ Olubadan, wọn yoo kede ijọba pajawiri nipinlẹ Oyo, nitori pe nnkan ko nii fararọ.
"Wọn wa n rọ ọ, mo ni ki wọn ma rọ ọ, ki wọn jẹ ko gbiyanju ẹ. Gomina to ba gbiyanju lati yọ Olubadan, wọn yoo kede ijọba pajawiri niluu yẹn lọjọ yẹn," Igboho sọ bẹẹ.
O ni kii ṣe ọrọ ẹnu lasan, nitori pe oun yoo dide lati tako iru igbesẹ bẹẹ, ti awọn eeyan yoo si dide lati ṣatilẹyin foun.
"Bi gomina kan ba gbiyanju ẹ, mo fi Ọlọrun bura, mi o fi ẹnu ṣe e. Lati Soka nibi ni Ibadan yoo ti maa mi titi," Igboho fidi rẹ mulẹ.
"Nigba ti ẹnikan tun wa sọ fun mi pe, wọn ni wọn yoo da Olubadan lọna, mo ni ko sẹni to to bẹẹ, wi pe ọrọ ẹyin ni. Nigba ti ko tii si iru agbara bayii lọwọ Olubadan, bi wọn ba lọ ka a mọle, wọn maa n ba a nibẹ ni.
"Ṣugbọn nigba ti agbara bayii tun ti wa lọwọ, ẹ wa sọ pe ẹ fẹ lọ ba baba mọle, miliọnu kan yin ko to bẹẹ. Bi ẹ ba gbiyanju ẹ, ẹ maa sa kuro ninu ile ijọba ni.
Bakan naa ni olori ajijangbara ọhun tun sọ pe oun ti fi ọkan Olubadan balẹ lati ma ṣe foya, nitori pe oun yoo ṣe atilẹyin fun un titi de opin.
Ninu ọrọ rẹ, o ni, "Mo sọ fun baba wa Olubadan wi pe ki wọn sun, ki wọn han oorun, ko sẹni to to bẹẹ, ti yoo wa ba a yin ninu ile, ọmọ ipinlẹ Oyo kan naa ni wa. Ara ipinlẹ Oyo ni Igboho wa, wọn ko tii pin wa.
"Baba Olubadan lo n beere fun ipinlẹ Ibadan, wọn ko sit ii buwọ lu, ipinlẹ Oyo naa la ṣi wa, a ko tii kọja aaye wa. Ki Ọlọrun jẹ ki ẹmi baba wa Olubadan gun," Igboho kadi ọrọ rẹ nilẹ.




























