Làásìgbò bẹ́ sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC Oyo, wọ́n ba ilé ẹgbẹ́, dúkìá àwọn olùdíje sípò gómìnà jẹ́

Oríṣun àwòrán, APC/FACEBOOK
Níṣe ni ọrọ di eni ori yọ o dile ni olu ile ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, bawọn ọmọ egbẹ kan ti inu n bi ṣe lọ da ile ẹgbẹ naa ru, ti wọn si le awọn oludije atawọn alaṣẹ ẹgbẹ naa danu kuro nibẹ.
Ni olu ile ẹgbẹ APC to wa ni Oke Ado ni ilu Ibadan ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iroyin ni awọn ọmọ ẹgbe oṣelu APC ti inu n bi pẹlu awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ni wọn lọ sile ẹgbẹ naa ti wọn si lọ da nnkan ru.
Ikọlu yii ni wọn lo waye fun bii wakati meji ko to di pe awọn ẹṣọ aabo da alaafia pada si ile ẹgbẹ naa.
Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo, Olawale Sadare bu ẹnu ate lu iṣẹlẹ naa ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ sawọn akọroyin.
Sadare ni awọn to ṣe ikọlu si ile ẹgbe naa ni wọn awọn ohun ija to lagbara dani to si jẹ pe niṣe ni wọn pọ ti wọn ko ohun ija naa wọ ile ẹgbẹ ọhun.
O fi kun pe iṣẹlẹ ṣokunfa biba awọn dukia awọn eeyan jẹ to fi mọ awọn ọkọ to jẹ ti awọn oludije atib tawọn alaṣẹ ẹgbẹ jẹ ati awọn ferese, ilẹkun, ile ẹgbẹ naa jẹ.
Ikọlu yii lo ti n mu ki awọn kan maa naka aleebu si eekan oloṣelu kan, to tun ṣẹṣẹ kuro nipo minisita fọrọ ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu pe oun lo wa nidii ikọlu naa.
Mi o mọ ohunkohun nipa ikọlu to waye si ile ẹgbẹ atawọn oludije mii - Adelabu
Amọ atẹjade kan ti agbẹnusọ Adelabu, Bolaji Tunji fi lede lọjọbọ sọ pe Adebayo Adelabu ko lọwọ ninu ikọlu naa.
Tunji ninu atẹjade naa sọ pe Adelabu ko ti ẹ si ni ipinlẹ Oyo lasiko ti ikọlu naa fi waye bi o ṣe jẹ pe o wa ni ilu Abuja lati lọ yanju awọn nnkan ti ko niiṣe pẹlu ohun to n lọ ni ipinlẹ naa.
O ni igbiyanju lati so Adelabu mọ iṣẹlẹ yii kii ṣe irọ lasan bikoṣe igbiyanju lati ba Adelabu ni orukọ jẹ ati gbogbo nnkan to ti n fi ọpọ ọdun ko jọ.
O fi kun pe ọpọ igba ni Adelabu ti maa n sọ pe wiwa ni iṣọkan, titẹle awọn ilana ati ofin, mimu eto iṣejọba tiwantiwa duro labẹnu ni o le mu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo ni ilọsiwaju.
Tunji tẹsiwaju pe Adelabu ni igbagbọ pe gbogbo ọna ti wọn ba fẹ gbe eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa gba, o pọn dandan fun gbogbo awọn ti ọrọ kan lati ni ajọsọ, ki wọn fẹnuko si ọna kan lai si ija dabi idaluru ki onikaluku si le fi ẹnu gun ibikan.
O wa rọ awọn eeyan lati kọti ọgbọin si iroyin tp n lọ pe Adelabu lo wa nidii ikọlu naa, pe awọn to kan fẹ ba agba oloṣelu naa lorukọ jẹ lo n gbe iroyin ẹlejẹ.
'O ṣeeṣe ki APC tun fidi rẹmi nibi eto idibo gomina ni ipinlẹ Oyo tawọn aṣiṣe to ṣẹlẹ ni 2023 ba tun waye'
Ẹwẹ, awọn oludije sipo gomina mẹfa ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo ti kọwe ranṣẹ si aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lati rawọ ẹbe si i lati da si ohun to n ṣẹlẹ ni APC ipinlẹ Oyo.
Awọn oludije naa, ninu iwe ti wọn kọ ranṣẹ si aarẹ fesun kan pe wọn n gbiyanju lati gbe oludije le awọn lori nibi idibo ọdun 2027.
Lẹta naa ti awọn oludije mẹfa pawọpọ buwọlu fi ẹhonu wọn han lori ohun ti wọn pe ni idunkoko si iṣọkan ẹgbẹ oṣelu APC ni Oyo.
Lara awọn ti wọn buwọlu lẹta naa ni Rauf Olaniyan, Adewale Kolapo Kareem, Musbau, Asanike, Akeem Agbaje, Oyedele Hakeem Alao ati Ololade Usman Bakare.
Awọn eeyan naa tun fẹsun kan pe awọn oludije sipo gomina n lo awọn ayederu eeyan lati fi da ẹgbẹ ru, ti wọn si n purọ pe awọn kan n ṣe atilẹyin fun wọn ni ẹsẹ.
Wọn ṣekilọ pe ṣiṣe ohun to mu ẹgbẹ APC fidi rẹmi ni ipinlẹ Oyo nibi eto idibo sipo gomina ni saa to kọja tun le ṣokoba fun ẹgbẹ naa nibi eto idibo 2027 to n bọ lọna.


























