Ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà ṣàbẹ̀wò sí Gómìnà Adeleke, ó ní kò sí jàǹdùkú olóṣèlú tí yóò fi ara ire lọ

Oríṣun àwòrán, Gov. Ademola Adeleke/X
Ọga agba awọn ọlọpaa pata l'orilẹ-ede Naijiria, IGP Olatunji Disu, ti ṣe abẹwo si ipinlẹ Osun latari rogbodiyan awọn janduku oloṣelu ti wọn n da omi alaafia ipinlẹ naa ru.
Ọjo Ẹti, ọjo Kẹta oṣu Keje ọdun 2026 ni Disu ṣe abẹwo naa, to si sọrọ pẹlu gomina ipinlẹ Osun, Ọmọọba Ademola Adeleke.
Eredi abẹwo naa bi ọga ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ, ni lati fi da awọn olugbe Ọsun loju pe ko si janduku oloṣelu ti yoo fi ara ire lọ lẹyin ipade alaafia ti oun wa fun yii.
O ni bo tilẹ jẹ pe idibo gomina n bọ lọna, ti awọn kan si ti n gbe igbesẹ to n fa rogbodiyan, sibẹ, ode yoo ro fawọn ti ko ba fi ọwọ sibi tọwọ n gbe.
'Idibo ni a n mura fun, ki i ṣe ogun'

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ lasiko abẹwo naa, IGP Disu sọ pe bi idibo gomina ṣe ku si dẹdẹ yii, ki ọlọmọ kilọ fun ọmọ rẹ.
Ọga ọlọpaa Naijiria naa sọ pe idibo ni ipinlẹ Osun n palẹmọ fun, ki I ṣe ogun jija.
O kilọ pe kawọn oloselu to n lo awọn janduku lati fi da omi alaafia ipinlẹ Ọsun ru tete jawọ bayii, ki wọn jẹ ki idibo naa lọ ni alaafia.
Bakan naa lo ni kawọn obi kilọ fun awọn ọmọ wọn pẹlu, ki wọn ma ṣe jẹ ki oloṣelu tabi ẹnikẹni lo wọn fun janduku ṣiṣe.
"Eti mi ti kun fun ọpọlọpọ ọrọ kobakungbe tawọn eeyan n sọ si mi ati sawọn ọlọpaa Naijiria latari rogbodiyan ati ipaniyan to waye l'Osun, amọ mo fi n da yin loju pe idibo yoo waye pẹlu irọrun.
"Ati pe eto aabo ti wa nilẹ fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu lati akoko ipolongo idibo onikaluku titi di ọjọ idibo ati lẹyin rẹ."
O ni awọn yoo ko ọpọ ọlọpọ wa sipinlẹ Osun fun idibo yii, oun yoo si ba awon oloṣelu sọrọ pẹlu.
Ni ipari ọrọ ọga agba Disu, o paṣẹ fun Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, Ibrahim Gotan, lati ṣe awari gbogbo awọn janduku to ti n da omi alaafia ipinlẹ naa ru, ki wọn si fi oju gbogbo wọn kata ofin.
Bakan naa ni Kọmisanna ajọ eleto idibo INEC, ẹka tipinlẹ Ọsun; Oluwatoyin Babalola, dupẹ lọwọ ọga ọlọpaa fun ọrọ ifinilọkanbalẹ to ba gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ọsun sọ.
Gomina Adeleke naa sọrọ
Gomina Ademola Adeleke ninu ọrọ rẹ, ṣalaye pe iṣakoso oun ko faaye gba jagidijagan tabi iwakiwawa yoowu to n waye nitori idibo to n bọ.
O fi kun un pe ẹni yowu tọwọ ba tẹ, bo ti wu kẹni naa nipo to, yoo jiya rẹ labẹ ofin.
Adeleke ṣalaye nipa bi rogbodiyan to waye kọja l'Osun ṣe ko o laya soke, to bẹẹ to pe ọga ọlọpaa Naijiria loruganjọ, ti Disu si dahun pẹlu idaniloju pe alaafia yoo jọba.
O ni oun gbagbọ ninu idaniloju ti IGP Disu fun oun yii, oun si gbagbọ pe ikọ ọlọpaa rẹ yoo ṣe bo ṣe yẹ lai fi sibi kan ṣaaju, lasiko idibo ati lẹyin rẹ.



























