Kò tọ́ kí àwọn kan máa fi òbítíbitì owó kun àtíkè lọ́jọ́ ìgbéyàwó nígbà tí ebi ń pa àwọn míì - Emir Zazzau

Emir ilu Zazzau, Ahmed Nuhu Bamalli

Oríṣun àwòrán, Ahmed Nuhu Bamalli

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Emire ilu Zazzau, Ahmed Nuhu Bamalli, ti ke si awọn obi ki wọn kilọ fun awọn ọmọ ki wọn dẹkun ati maa na obitibiti owo lori aṣọ ẹbi lasiko igbeyawo wọn.

Bamalli lo sọrọ naa nibi ayẹyẹ ogun ọdun ajọ Crystal Muslim Organisation (CMO) niluu Abuja.

O ni kaka ki awọn to n ṣe igbeyawo maa na irufẹ owo bẹẹ lọjọ igbeyawo wọn, niṣe lo yẹ ki wọn fi ṣaanu fun awọn alaini.

Emir naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe nnkan le koko ni Naijiria, ọpọ awọn mọlẹbi ti wọn ri jajẹ ni wọn n na ẹgbẹgbẹrun owo lori igbeyawo awọn ọmọ wọn dipo ki wọn fi irufẹ owo bẹẹ ṣaanu, eyii to tunbọ n ṣafikun iwa ibajẹ lawujọ.

O ni "Ẹ maa ri awọn eeyan wa ti wọn n fi obitibiti owo ṣe oju ọmọ to n ṣe igbeyawo loge tabi ki wọn ra aṣọ ẹbi ti iye rẹ to idaji miliọnu kan tabi N200,000 tabi N300,000, eyii ti ko ṣe itẹwọgba lọdọ temi.

"Ọpọ eeyan lo wa ni igboro ti wọn ko ri ounjẹ jẹ lẹẹmẹta loojọ. Eyii wọnpọ lawujọ wa, amọ awa kan ti sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Nitemi, mi o tii na epinni kan ri lori aṣọ ẹbi tabi atike fun ọmọ to n lọ sile ọkọ. Ti iya rẹ ba yan lati na owo naa, wahala awọn mejeji niyẹn… amọ mi o jẹ ṣe iru rẹ laye."

Emir naa sọ pe kii ṣe pe oun ni ki awọn eeyan ma na owo lori igbeyawo ọmọ wọn o amọ kii ṣe ni aṣeju.

O tẹsiwaju pe "E ni lati ba ara wa sọ ootọ ọrọ, a ko nilo irufẹ nnkan bẹẹ pẹlu bi ọrọ aje ilẹ wa ṣe ri lọwọ yii.

"Nitori naa mo n parọwa si gbogbo yin ki ẹ ṣe jẹjẹ ki ẹ si wo nnkan ti yoo mu aye yin dẹrun si, ohun ti yoo fun yin lominira, ati ohun ti yoo mu irẹpọ waye lawujọ yin.

"Nitori ti ẹ ba n jaye ti ara adugbo yin ko si ri ounjẹ oojọ jẹ, wahala yoo ṣẹlẹ o."

Lẹyin naa lo rọ ijọba ki wọn pese eto ẹkọ ọfẹ fun awọn alaini.

O tun rọ awọn Musulumi ki wọn maa ṣetọrẹ aanu fun awọn alaini ni gbogbo igba nitori o jẹ ohun to ṣe itẹwọgba niwaju Allah.