Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí owó ò rẹ tí CBN bá gbẹ́sẹ̀lé ilé ìfowópamọ́ tí ò ń lò, pẹ̀lú bí o ṣe lè rí owó rẹ̀ gbà padà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ọjọru, ọjọ Kiini, oṣu Keje ti ile ifowooapọ agba Naijiria ti kede gbigbẹsẹle iwe aṣẹ awọn ile ifowopamọ alabọde mẹrindinlaadọta ni awọn eeyan paapaa awọn iyalọja ti wọn maa n lo ile ifowopamọ alabọde ti wa ninu inu fu aya fu.
Nigbakigba ti irufẹ iṣẹlẹ bayii ba waye niṣe ni ibẹrubojo maa n ba awọn eeyan nipa pe ki lo maa ṣẹlẹ si owo wọn.
Fun idi eyi, BBC ba alakooso tẹlẹ ri fun ile ifowopamọ kan, Muhammad Abubakar sọrọ to si ṣalaye pe awọn ofin wa ti ijọba ti la kalẹ lati le ri daju pe awọn eeyan ko padanu owo wọn patapata nigba ti irufẹ iṣẹlẹ bayii ba waye.
Abubakar ni gẹgẹ bi ofin, o ni iye ti eeyan le fi sile ifowopamọ to jẹ pe eeyan ko le padanu owo naa bi ile ifowopamọ bẹẹ ba kogba sile.
O ṣalaye pe fun awọn ile ifowopamọ nla, miliọnu marun-un naira ni iye ti owo naa, to si jẹ miliọnu meji naira fun awọn ile ifowopamọ alabọde bi iru eyi ti ijọba gbẹsẹle iwe aṣẹ wọn yii.
O ni ti eeyan ba ni ju awọn owo yii lọ lawọn ile ifowopamọ ti CBN ba gbẹsẹle, o ni awọn ilana ti CBN maa gba ti wọn fi maa fun wọn ni owo naa pada amọ wọn ko le tete rii gba.
"Fun iru iṣẹlẹ yii, awọn ti owo wọn ko ba ju miliọnu meji naira lọ wa silẹ ṣeeṣe ki wọn ri owo gba lẹẹkan naa.
"Fun awọn ti owo wọn ju bẹẹ lọ, miliọnu meji naira ni wọn maa kọkọ fun wọn, wọn maa ṣe suuru ti CBN fi maa ta ohun ini ile ifowopamọ naa, ti wọn si maa san owo naa fun wọn diẹdiẹ."
Bawo lawọn eeyan ṣe maa ri owo wọn gba pada?
Abubakar ni nigba iṣẹlẹ bayii, ajọ adojutofo to n mojuto ti eeyan ba fi sile ifowopamọ iyẹn Nigeria Deposit Insurance Corporation, NDIC lo maa n gbakoso owo to ba wan nile ifowopamọ ti wọn gba iwe aṣẹ rẹ.
Ajọ yii maa ṣe iwadii awọn eeyan to lowo ni ile ifowopamọ bẹẹ nipasẹ BVN wọn, ti wọn si maa san owo ti wọn ni ninu banki naa sinu akoto banki mii ti wọn ba ni.
O ni awọn ti wọn ba ni ju miliọnu meji naira lọ maa lọ forukọ silẹ pẹlu NDIC ki wọn le ri gbogbo owo to ba ku gba pe.
O fi kun pe awọn ti ko ba ni banki mii ti wọn n lo maa nilo lati lọ si NDIC lati ṣayẹwo wọn, ki wọn si mọ ọna mii ti wọn fi maa san owo wọn fun wọn.
Wo àwọn báǹkì alábọ́de 46 tí CBN gba ìwe àṣẹ wọn àti ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀

Oríṣun àwòrán, KC Nwakalor/Bloomberg via Getty Images
Banki apapọ Naijiria, CBN ti kede pe oun ti gbẹsẹle iwe aṣẹ awọn ile ifowopamọ alabọde mẹrindinlaadọta ni Naijiria.
Gẹgẹ bii atẹjade kan ti agbẹnusọ banki ọhun, Hakama Sidi-Ali fi lede, o ni lẹsẹkẹsẹ ni aṣẹ naa yoo bẹrẹ si n mulẹ.
Atẹjade naa sọ pe, "Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2026, banki apapọ Naijiria, CBN ti wọgile iwe aṣẹ iṣẹ awọn ile ifowopamọ mẹrindinlaadọta gẹgẹ bii agbara ti abala kejila ati ikẹtala ofin ile ifowopamọ ti ọdun 2020 fun."
Gomina CBN, Olayemi Cardoso lo buwọlu gbigbẹsẹle iwe aṣẹ awọn ile ifowopamọ naa latari pe wọn kuna lati ni awọn amuyẹ to yẹ gẹgẹ bii ile ifowopamọ.
Eredi ti CBN fi wọgile iwe aṣẹ awọn banki naa
CBN mẹnuba idi marun un ọtọtọ to fi gbe igbesẹ gbibẹsẹle iwe aṣẹ awọn ile ifowopamọ naa.
Akọkọ ni pe awọn ile ifowopamọ ọhun ko ni owo to to ni ipamọ lati san fun awọn onibara wọn to ba kogbawọle.
Ekeji ni pe wọn n pari awọn iṣẹ kan lai kọkọ gba aṣẹ lọwọ CBN.
Ẹkẹta ẹsun ti CBN fi kan wọn ni pe wọn ko ṣiṣẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
CBN ni wọn tun kọ lati bẹrẹ iṣẹ laarin oṣu mejila ti wọn gba iwe aṣẹ lati maa ṣiṣe.
Nigba ti ẹsun karun un jẹ kikuna lati ni iye owo to yẹ ni apo wọn lai padanu iye kankan ninu owo ọhun.
Awọn ile ifowopamọ ti ọrọ naa kan ree
- Minji-Se Churchill MFB
- Merchant MFB
- Janmaa MFB
- Busu MFB
- Gold MFB
- Zain MFB
- Bompai MFB
- Ajwa MFB
- NOW NOW Digital MFB
- Crystabel Microfinance Bank
- Chanelle MFB
- Abia SME MFB
- Kamba MFB
- Iwade MFB
- Winview MFB
- ru MFB
- Minjibir MFB
- Shanono MFB
- Sumaila MFB
- Rimin Gado MFB
- Mwaghavul MFB
- camore MFB
- TOFA MFB
- Safegate MFB
- Creekline MFB
- Bestar MFB
- Livingspring MFB
- ple MFB
- Stanford MFB
- Frontline MFB
- Zafec MFB
- Supreme MFB
- Bejin-Doko MFB
- Kanopoly MFB
- Bellbank MFB
- Yeneng MFB
- Creditville MFB
- MBAG MFB
- Sraight Sahara MFB
- OurPass MFB
- Verdant MFB
- Basawa MFB
- Casha MFB
- Esteem MFB
- Entrepreneur MFB
- Avantus MFB
CBN sọ pe afojusun oun ni lati lati ri daju awọn ile ifowopamọ to n ṣiṣẹ ni Naijiria ni awọn amuyẹ to tọ lati ko araalu sinu gbese kankan.



























