Emi ò lówó tí màá fún àwọn èèyàn Osun láti dìbò fún mi o- Olajide Esan, Olùdíje sípò gómìnà fún AAC

Olajide Esan, oludije fun ipo gomina Osun

Oríṣun àwòrán, Olajide Esan /Facebook

Àkọlé àwòrán, Olajide Esan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ba a ti ṣe la a wi, ẹni kan ki I yan ana rẹ lodi ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Osun ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC); Olajide Esan, fi ọrọ rẹ ṣe nigba to kede pe oun ko ni kọbọ toun yoo fun araalu ki wọn le dibo foun, bi ko ṣe pe igbagbọ wọn ninu ohun ti oun le ṣe fun Osun lo ṣe koko.

Oludije yii sọ pe iṣẹ ilu ni Ọlọrun gbe le oun lọwọ, oun fẹ sin ipinlẹ Osun ni, ko ba owo de.

Olajide sọrọ yii lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2026 yii, nibi itakurọsọ ti ileeṣẹ BBC News Yoruba gbe kalẹ fawọn to fẹ di gomina ipinlẹ Osun ninu ibo to ku si dẹdẹ naa.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu AAC ti Omoyele Sowore n dupo aarẹ Naijiria labẹ rẹ naa sọ pe:

" O di ọjọ ti araalu ba mọ pe wọn n jẹun ọmọ ninu oyun ni pẹlu owo ti wọn n gba lọwọ oṣelu, ko too ye wọn pe ohun to yẹ ki wọn jẹ́ ni wọn n jẹ.

"Emi o ni owo ti mo maa fun araalu lati dibo fun mi o, bi ẹ ba ri ẹlomi-in ti ẹ ro pe o tun kunju oṣuwọn ju mi lọ, to fẹẹ sinlu ju mi lọ, ẹ lọọ dibo fun un."

Ki lo mu Olajide sọrọ bẹẹ?

Olajide Esan

Ṣaaju ni Esan ti sọ pe oun ki i ṣe oloṣelu ni toun, o ni awọn oloṣelu to n lewaju Naijiria ko sin araalu, bi ko ṣe pe araalu gan-an lo n sin wọn.

Gẹgẹ bi Olajide ṣe wi:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"A gbe ẹgbẹ AAC kalẹ nitori a ri I pe ọpọlọpọ kudiẹ-kudiẹ lo wa ninu ijọba ṣiṣe, ijọba ṣiṣe lorilẹede yii ti da bii bamubamu ni mo yo, awọn o mọ boya ebi n pa ọmọ ẹnikọọkan.

" Oṣelu ka tẹ ori araalu ba, ka yan araalu jẹ lo wa lorilẹede yii, ka fiya jẹ araalu to fi jẹ pe to ba ti di asiko ibo, ti a fun wọn ni ẹgbẹrun marun-un si mẹwaa, ki wọn le maa tẹwọ gba a.

"Awa si wo o pe ko gbọdọ maa ri bẹẹ lọ, ki orilẹede yii le ni ọjọ ọla."

Lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, Olajide ṣa akawe eto kan ti ijọba pe ni "Vision 2020" nigba kan, eyi to jẹ afojusun fun ọdun naa, ti ko si pada wa si imuṣẹ.

Bi a ba fẹ ki nnkan yatọ nilana oṣelu, ti ki I ṣe pe adura nikan ni ọmọ Naijiria yoo ṣaa maa gba pe ki nnkan yipada, oludije yii sọ pe afi kawọn eeyan Osun ti idibo kan lọtẹ yii dibo lọna ọtọ fun oun ti Olodumare pe fun iṣẹ ilu.

"Ikooko ọbẹ ni araalu jẹ fun oloṣelu, ko gbọdọ fọ. Oloṣelu ko gbadura ki araalu gbọn mọ wọn lọwọ. Idi niyẹn ti mo fi fẹẹ ṣe temi lọna ọtọ."

Mo ni eto ti a pe ni "Osun Residence Data Base" ti yoo jẹ ka mọye eeyan to wa l'Osun

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Olajide Esan sọ pe ohun ti oun mu ni pataki ni gbigba ijọba fun araalu, nigba ti araalu ba ti le sọ ohun ti wọn fẹ.

O ni eto kan toun pe ni Osun Residence Data Base yoo jẹ koun mọ iye agba ati ọmọde to wa l'Osun ati ohun ti wọn n fẹ, ti ko fi ni fi sibi ikan ju ibi kan lọ.

Bakan naa lo ni oun tun ni eto mi-in ti yoo ri si iṣuna, o pe e ni Financial Dashboard.

"Eyi yoo jẹ kawọn ara ipinlẹ Osun mọ iye to n wọ apo ijọba, yoo jẹ ki wọn mọ iye ti ijọba n na lọwọ ati iye to ku lapo ijọba, to jẹ pe ti naira kan wọn ba sọnu, wọn yoo le beere pe, 'Gomina, naira kan wa da."

O ni awon ijọba kan ti jẹ gbese silẹ l'Osun de awọn ọmọ ipinlẹ yii, araalu kọọkan si ti jẹ gbese miliọnu kan naira, o si yẹ ki araalu maa beere bi wọn ṣe n nawo wọn

Bakan naa lo ni oun tun ni eto ti yoo ri si ẹtọ araalu, nibi ti wọn yoo ti maa gbọ ifisun awọn eeyan Osun, ti wọn yoo si maa dajọ are fun alare, da ti ẹbi fun ẹni to ba jẹbi.

A ni eto ti awọn ọlọpaa yoo fi maa mọ ibi tawọn ti ajinigbe ji gbe ba wa

Lori eto aabo to mẹhẹ lorilẹede yii, Esan sọ pe boun ba di gomina Osun, oun ti ni eto ti yoo jẹ kawọn ọlọpaa maa mọ ibi ti awọn ti wọn ba ji gbe ba wa.

O ni ọlọpaa ko ni I maa jokoo si ọfiisi wa ẹni ti wọn ji gbe mọ, bi ko ṣe pe ijọba oun yoo ra ọkọ ti wọn yoo maa fi wọdẹ lati mọ ibi tawọn ajinigbe ba wa pẹlu ẹni ti wọn ji gbe.

Bakan naa lo sọrọ nipa rogbodiyan ẹgbẹ awakọ ero l'Osun, (NURTW) eyi to bẹrẹ si i ṣẹlẹ nigba ti ibo ku si dẹdẹ yii. Oludije ninu ẹgbẹ AAC yii sọ pe:

"Awọn awakọ ero to n wa ọna lati ni anfaani si gbigbe awọn iwe idibo atawọn nnkan ẹlẹgẹ mi-in lasiko idibo lo wa nidii rogbodiyan to n waye naa."

O fi kun un pe awọn eeyan tawọn oloṣelu ti wọle si lara, ti wọn n ri lo naa lo wa nidii nnkan wọnyi.

"Ẹgbẹ AAC nikan ni ko ni Baba Isalẹ"

Nigba to n dahun ibeere lori nini Baba Isalẹ to n tukọ ẹgbẹ kọọkan labẹnu, Olajide ṣalaye pe ẹgbẹ AAC nikan ni ko ni Baba Isalẹ ni Naijiria.

O ni ifarajin ni ẹgbẹ AAC ni, wọn ko tẹle ilana "Baba sọ pe" to wa nilẹ lorilẹede yii.

Olajide fi kun un pe idi niyẹn ti oun fi ni i lọkan lati gba awọn ọba alaye kuro labẹ awọn oloṣelu ti wọn ti maa n sa kubẹkubẹ, ti ọba fẹrẹ le maa fi aya kanlẹ fun oloṣelu.

O loun yoo ṣeto kan to pe ni Osun Agro Trade Economy, eyi to ni ko si iru rẹ lagbaaye, ti yoo mu ijọba ibilẹ kọọkan ni eto okoowo ti wọn yoo maa ṣe, ti ọrọ aje yoo si maa gbooro.

Gbogbo eyi ni Esan sọ pe oun yoo ṣe pẹlu akoyawọ gidi.

Ta a ni Olajide Esan?

Olajide Esan

Oríṣun àwòrán, Olajide Esan/Facebook

Ilu Ejigbo, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi Olajide Esan ni ọdun 1986.

O kẹkọọ gboye BSC ninu imọ nipa Geography and Resource Management nile ẹkọ giga UNIOSUN.

Bello Muideen Yekeen ni ẹni to yan lati ṣe Igbakeji ninu idije si ipo gomina ipinlẹ Osun to ti n kopa.

Oniṣowo ọkọ ayọkẹlẹ ni Olajide Esan.

Igba gbogbo lo maa n sọ pe oun kunju oṣuwọn ju awọn oludije yoku lọ, owo nikan ni oun ko ni lọwọ.