Ìjoba àpapọ̀ kó oògùn ìbílẹ̀ tó lè wo àìsàn jejerẹ, ẹ̀jẹ̀ ríru, jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ àtawọn àrun míì jáde

Asiko ti wọn n ko oogun naa jade

Oríṣun àwòrán, Punch

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọna ati gbaruku ti awọn ileeṣẹ to n poogun labẹle ni Naijiria, ijọba apapọ ti ṣi aṣọ loju eegun oogun ibilẹ meje to le koju oniruru arun bii jẹjẹrẹ, ẹjẹ riru, arun jẹdọjẹdọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ajọ Nigeria Natural Medicine Development Agency, NNMDA, lo ko awọn oogun naa jade.

Gẹgẹ bii ohun ti ajọ NNMDA sọ, o le ni oogun ibilẹ mejilelogun ti wọn ti po ni Naijiria lati koju oniruru arun lati ọdun 2023.

Minisita to n ri si imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Ọmọwe Kingsley Udeh lo ṣi aṣọ loju awọn oogun naa lasiko ayẹwo rẹ si ọọfisi NNMDA niluu Eko.

Lasiko abẹwo naa lo tun pade awọn agbontarigi ni ẹka oogun pipo lati jiroro lori bi wọn yo ṣe po oogun naa.

Ude sọ pe ẹgbẹlẹbẹ ewe ati egbo lo wa ni Naijiria to si le wo oniruru aisan.

Ninu ọrọ minisita ọhun, ewe ati egbo lo n gbọ aisan awọn eeyan ni igberiko fun ọpọ ọdun sẹyin, awọn ewe ati egbo naa ko si tii dawọ iṣẹ duro titi si asiko yii.

O tun ṣeleri pe awọn yoo ṣe idasilẹ ajọ Clinical Observational Research Centre laipẹ, eyii ti yoo ri si bi wọn yoo ṣe maa pese owo fun iwadii nipa ewe ati egbo fun iwosan ni Naijiria.

Lẹyin naa lo gboriyin fun awọn adari ajọ naa fun iṣẹ takuntakun wọn lori aṣeyọri ọhun.

O ni inu oun dun pupọ fun aṣeyọri naa ati pe wọn ti n po ewe ati egbo sinu koro bayii ko le rọrun lati lo fun awọn eeyan.

Ọga agba ajọ NNMDA, Martins Emeje sọ pe iṣẹ ti egboogi ibilẹ n ṣe ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin.

Emeje ni asiko tito ki a maa po oogun ti a n lo ni Naijiria dipo ki a maa duro de awọn ileeṣẹ ilẹ okere fun igbala wa.

O ni "Ọkan lara awọn oogun ti a ko jade lonii lagbara lati pese iṣẹ miliọnu mẹta ati abọ ti a pari pari rẹ tan.

Lara awọn arun ti wọn ni awọn oogun ibilẹ naa le wo ni prostate cancer, colorectal cancer, peptic ulcer disease, ẹjẹ riru, high cholesterol ati hepatitis B.