Mo máa ṣiṣẹ́ tayọ Gómìnà Adeleke àtàwọn olùdíje yòókù tí mo bá wọlé ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun - Olùdíje AAC

Oríṣun àwòrán, Olajide Esan/X
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu AAC nipinlẹ Osun, Olajide Esan, ti sọ pe oun ni ore ọfẹ lati tayọ ju awọn alatako oun lọ ti wọn ba yọ ti owo kuro nibẹ.
Esan sọ fun BBC Yoruba wi pe nnkan to mu oun wọ inu eto oṣelu ni pe awọn oloṣelu lo pọ Naijiria, ṣugọn ko si adari to pọ.
Oludije sipo gomina ẹgbẹ AAC ni oun loun le ṣoju araalu bi o ti tọ ati bi o ti yẹ tori oun yoo ṣejọba gẹgẹ bii adari.
Lara afojosun Esan ni lati ṣatunṣe eto iṣejọba ipinlẹ Osun eyi ni o kudiẹ kaato lọwọ yii.
Esan fikun ọrọ rẹ wi pe nnkan mii ti oun ati ẹgbẹ AAC yoo ṣe toun ba wọle ni lati ni akọsilẹ awọn eeyan ipinlẹ naa lati mọ nnkan ti wọn nilo gan an.
O ni gbogbo oniṣẹ ọwọ ni wọn yoo ri iṣẹ ṣe ti oun ba wọle ibo gomina ipinlẹ Osun.
Oludije sipo gomina AAC sọ pe aparo kan ko ga ju ọkan lọ ninu ẹgbẹ oun, ati pe ko si baba isalẹ kankan foun.
Esan wa rọ gbogbo araalu lati dibo fun ijọba ti yoo ṣe nnkan ti wọn n fẹ.






