Mọ̀ nípa Abu-Bilal al-Minuki, agbéṣùmọ̀mí ti ikọ̀ ológun Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà pawọ́pọ̀ ṣekúpa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Karun-un ni ijọba Naijiria ati Amẹrika kede pe awọn ti ṣekupa Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ igbakeji olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS.
Lati igba ti wọn kede iroyin naa ni awọn eeyan ti n wadii lati mọ nipa iru eeyan ti Abu-Bilal al-Minuki jẹ.
BBC kan si Dokita Kabiru Adamu, ẹni to jẹ olori ileeṣẹ Beacon Security Limited, to tun jẹ onimọ nipa eto aabo ni ẹkun Sahel ati Dokita Audu Bulama Bukarti, ẹni to oniwadii nipa awọn agbeṣumọmi ni ilẹ Africa.
Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọkùnrin náà rèé
Kabiru ni Abubakar Ibn Muhammad Ali ni orukọ Abu-Bilal al-Minuki gan ti awọn obi rẹ sọ ọ.
O darapọ mọ ikọ ISWAP to jẹ ẹya ISIS ni ẹkun iwọ oorun Africa, to si ti ṣe iranwọ fun ikọ naa lati ni ọmọ ẹgbẹ to pọ gan lati igba to ti darapọ mọ wọn.
Gẹge bi onimọ naa ṣe sọ, Abu-Bilal al-Minuki ni imọ pupọ nipa igbesumọmi atawọn ọgbọn inu nipa ọna ti wọn fi le ṣe ikọlu atawọn ọna ti wọn fi le moribọ lọwọ awon Ologun Naijiria.
Abu-Bilal al-Minuki wa lara awọn agbeṣumọmi to bori Shekau.
O fi kun pe Abu-Bilal al-Minuki ko ni ibaṣepọ to danmọran pẹlu Mamman Nur ati Abubakar Shekau ti wọn figba kan jẹ eekan ninu ikọ naa.
Lẹyin ti Abu-Bilal al-Minuki ṣekupa Shekau Mamman Nur di ilu mọọka.
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ni al-Mainuki ni igbakeji olori awọn ikọ ISIS ṣugbọn Dokita Bukarti ni bẹẹ kọ ni ọrọ ri, pe abẹṣinkawọ ISIS lo jẹ.
"Eekan gboogi ni ISWAP, to si maa n mojuto ikọ ISWAP ni ẹkun Lake Chad, to fi maa n mojuto bi wọn ṣe n pa owo wọle fawọn agbeṣumọmi naa.
Dokita Kabiru Adamu ni Abu-Bilal al-Minuki tun jẹ ọmọ ẹgbẹ Maktar Al-Furkqan to jẹ ẹka ikọ agbeṣumomi ISIS.
O fi kun pe Abu-Bilal al-Minuki wa lara awọn eeyan ti ijọba Amẹrika kede orukọ wọn pe wọn n ṣe atilẹyin fawọn agbeṣumọmi kaakiri agbaye.
Ipa wo ni Abu-Bilal al-Minuki n ko ninu ikọ ISIS?
Dokita Kabiru Adamu ni ipa lo lagbara ni Abu-Bilal n ko ninu bi ikọ ISIS ṣe n ṣiṣẹ kaakari agbaye.
O fi kun pe ko lọwọ ninu ikọlu to waye ni Naijiria tabi iwọ oorun lapapọ nitori ipo rẹ ko si nipa ogun jija.
"Olori ni ninu ikọ naa amọ kii ṣe olori niwaju ogun.
O sọ pe Abu-Bilal jẹ to maa n ṣe akoso bi ohun ṣe maa n lọ loju ogun amọ kii kopa loju ija gangan nibi ti wọn ti n pa awọn eeyan.
Yatọ si pe o jẹ ọmọ ọgbẹ ẹka 'Maktar Al-Furkqan, o tun wa lara awọn to si jẹ ọkan lara awọn ọga agba to n dari ikọ naa.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria àti Amẹrika gbẹ̀mí igbákejì ẹgbẹ́ ISIS, Abu-Bilal al-Minuki

Oríṣun àwòrán, Getty
Ijọba apapọ ti fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika ti ṣekupa Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lo fidi eyii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede laarọ ọjọ Abamẹta.
Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti kọkọ kede igbesẹ naa.
Ninu ọrọ Tinubu, o ni orumọju ni wọn gbẹmi olori ẹgbẹ alakatakiti ọhun.
Nigba ti Aarẹ Trump n juwe Abu-Bilal al-Minuki, o ni oun ni igbakeji ẹgbẹ ISIS kaaliri agbaye.
Ki ni Tinubu sọ?
Ninu ọrọ to fi lede loju opo Facebook rẹ, Tinubu sọ pe gbigbẹmi olori agbesunmọmi naa n ṣapejuwe ibaṣepọ to wa laarin ijọba Naijiria ati Amẹrika lati rẹyin igbesunmọmi.
O ni "Awọn ọmọ ogun wa pẹlu ajọṣepọ pẹlu awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika, kọju ija to lagara si ẹgbẹ Islamic State.
"Ayẹwo lẹyin ikọlu naa fidi rẹ mulẹ pe a ti ṣekupa olori ẹgbẹ ọhun ti wọn ti n wa fun ọjọ pipẹ, Abu-Bilal Al-Manuki, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu-Mainok, toun ti ọpọ awọn ẹmẹwa rẹ lẹyin ado oloro sinu ọgba wọn to wa ni Lake Chad Basin.
"Naijira mọ riri ajọṣepọ rẹ pẹlu Amẹrika lori ọrọ yii. Mo si dupẹ gidigidi lọwọ Aarẹ Trump fun idari ati atilẹyin rẹ lori igbiyanju yii.
"Mo tun gboriyin fun awọn ọmọ ogun to ṣiṣẹ ni iha mejeji, mo si ni afojusun pe a tun maa kọlu ọpọ ibuba awọn agbesunmọmi mii kaakiri orilẹede yii."
Ki ni Aarẹ Trump sọ?
Ninu ọrọ Aarẹ Trump lo ti kede pe ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede mejeji ti ṣaṣeyọri lati gbẹmi ogboju agbesunmọmi ọhun.
O ni olori agbesunmọmi naa ni "Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ igbakeji ẹgbẹ ISIS kaakiri agbaye, to ro pe oun le lọ farapamọ si Afrika…."
Trump sọ pe Abu-Bilal al-Minuki ko ni le maa ṣeruba awọn eeyan Afrika mọ bayii lẹyin to ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ ijọba Naijiria fun ibaṣẹpọ rẹ lati rẹyin Abu-Bilal al-Minuki.




























