Iléeṣẹ́ ọmogun dóòlà ìyàwó ọ̀gágunfẹ̀yìntì tó kú sí àkàtà àwọn jàndùkú agbébọn lẹ́yìn tí wọ́n sin ọkọ rẹ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ọmogun Naijiria ti kede pe awọn ti doola Arabinrin Amina Abubakar to jẹ iyawo Ọgagunfẹyinti Rabe Abubakar to ku si akata awọn ajinigbe nipinlẹ Katsina.

Alukoro fun ileeṣẹ ọmogun Naijiria, Ọgagun Samaila Uba, lo fọrọ yii lede lalẹ ọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.

Ni bi ọsẹ meloo kan sẹyin lawọn agbebọn ji tọkọ taya naa gbe ki iroyin iku Ọgagunfẹyinti Abubakar to jade lọjọ Aiku to kọja.

Ọgagun Uba ni ikọ Operation FASAN YAMMA lo doola iyawo oloogbe naa lọwọ awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ ologun sọ pe ni abule Tunga lawọn ọmogun ti kọju ija sawọn janduku agbebon naa, ti wọn si doola arabinrin Amina.

Alukoro ileeṣẹ ologun ni awọn janduku agbebọn naa yinbọn fun iyawo ọgagun Abubakar ki wọn to fẹsẹ fẹẹ.

Ni bayii, a gbọ pe Arabinrin Amina n gba itọju lọwọ nile iwosan awọn ologun.

Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun Naijiria ti ṣeleri wi pe awọn yoo fun Arabinrin Amina ni itọju to peye titi ti ara rẹ yoo fi ya daadaa.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn ọmogun ko ni kaarẹ nipa kikọju ija sawọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ ni Naijiria.

Iléeṣẹ́ ọmogun ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí ẹbí Ajagunfẹ̀yìntì Rabe Abubakar tó kú sí àkàtà àwọn jàndùkú agbébọn

Ileeṣẹ ọmogun Naijiria ti ṣabẹwo ibanikẹdun si ẹbi ajagunfẹyinti, Maj Gen Rabe Abubakar, to ku si akata awọn janduku ajinigbe nipinlẹ Katsina.

Ikọ ọmogun Naijiria ti Ọgagun IM Abdullahi ko sodi lo ṣabẹwo si ẹbi oloogbe ati ijọba ipinlẹ Katsina lọjọ Aiku.

Ikọ naa fi iṣẹ ibanikẹdun ọga agba ileeṣẹ ologun Naijiria, OO Oluyede, jẹ fun ẹbi oloogbe ati ijọba Katsina.

Ọgagun Abdullahi ṣapejuwe oloogbe ọgagun Abubakar gẹgẹ bi olufọkansin to fi gbogbo agbara rẹ sin orilẹede Naijiria.

Ọgagun Abdullahi to jẹ ọkan lara awọn ọga agba nileeṣẹ ologun fi da ẹbi oloogbe naa loju pe ileeṣẹ ologun yoo ri pe awọn to wa nidii iku Ọgagun Abubakar foju wina ofin.

Abdullahi tun sọ fun ẹbi oloogbe wi pe ileeṣẹ ologun yoo gbaruku ti wọn lasiko yii.

''Ọgagun Abubakar ṣiṣẹ takun takun nileeṣẹ ologun Naijiria fun ọgbọn ọdun.

Ileeṣẹ ologun ko ni jẹ ki gbogbo iṣẹ ti ọgagun Abubakar ṣe fun Naijiria lọ lasan an.

Iṣẹ ti Ọgagun Abubakar ṣe yoo maa tẹsiwaju lati maa jẹ iwuri fawọn ọmogun Naijiria,'' Ọgagun Abdullahi lo sọ bẹẹ.

Ikọ ologun naa fun ẹbi oloogbe ni asia orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ami iyi fun ipa ribi ribi ti Ọgagun Abubakar ko nileeṣẹ ologun Naijiria nigba aye rẹ.

Alhaji Dikko Mu'azu Ruma lorukọ gbogbo ẹbi oloogbe dupẹ lọwọ ikọ ologun to ṣabẹwo si ẹbi Abubakar.

Ṣaaju ni ikọ ologun naa ti kọkọ ṣabẹwo si ijọba ipinlẹ Katsina nibi ti Igbakeji Gomina Mallam Faruk Lawal Jobe ti ṣoju gomina ipinlẹ Katsina.

Igbakeji Gomina sọ pe iku Ọgagun Abubakar jẹ nnkan to bani lọkan jẹ fun ipinlẹ Katsina ati fun gbogbo orilẹede Naijiria.

Mallam Jobe wa pe fun ifọwọsowọpọ gbogbo eeyan lati wa ojutuu si iṣoro awọn agbebọn to n fẹmi awọn eeyan ṣofo.

"Inú ìrora ńlá la wà" Ọmọbìnrin Ọ̀gágunfẹ́yìntì Rabe Abubakar, táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, sọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀

Wọn ti sin oku Ọgagunfẹyinti Rabe Abubakar to ku sinu ahamọ awọn ajinigbe lẹkun iwọoorun ariwa orilẹede Naijiria.

Aarẹ Tinubu ti kọminu lori iṣẹlẹ naa, o siti ba awọn ẹbi kẹdun pẹlu ileri pe awọn igbesẹ to lagbara yoo waye lati kọlu awọn ẹgbẹagbesunmọmi to n ṣọṣẹ lagbegbe gbogbo kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ ti ọmọbinrin oloogbe naa, Bilikisu Rabe Abubakar sọ fun BBC News, O ni inu irora nla lawọn ẹbi oloogbe naa wa bayii lẹyin ijinigbe ati iku rẹ.

Bilikisu ṣalaye pe wọn sin oku ọgagunfẹyinti naa ni irọlẹ ọjọ kan naa ni ibamu pẹlu ilana ẹsin musulumi.awọn alaṣẹ sọ pe inu ahamọ awọn ajinigbe naa lẹyin ti ilera rẹ mẹhẹ lori ohun ti wọn sọ pe o rọ mọ aisan itọ ṣuga ati ẹjẹ riru.

Ipinlẹ Katsina ni wọn ti ji ọgagunfẹyinti naa ati iyawo rẹ gbe.

Titi di asiko yii, ko tii si ẹni le sọ ni pato ibi ti iyawo ọgagun agba naa, Hajiya Amina Abubakar wa. Ẹbi rẹ sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ abo gbogbo ti fi ọkan awọn balẹ pe wọn n gbe gbogbo igbesẹ lọwọlọwọ lati gba itusẹ rẹ.

Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Rabe Abubakar táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ti kú sí àkàtà àwọn jàndùkú ajínigbé

Ọgagunfẹyinti nileeṣẹ ologun Naijiira, Maj Gen Rabe Abubaka, tawọn agbesunmọmi ji gbe pẹlu iyawo rẹ nipinlẹ Katsina lapa ariwa Naijiria ti ku bayii si akata awọn janduku ajinigbe.

Adari eto iroyin fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Maj Gen Samaila Uba, lo fi idi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti o fi sita lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa yii.

Ọgagun Uba ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni ileeṣẹ ọmogun Naijiria fi kede iku ajagunfẹyinti Abubakar.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ologun ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi atawọn akẹgbẹ Ọgagun fẹyinti naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiria ṣapejuwe ajagunfẹyinti Abububakar gẹgẹ bi akinkanju to fi tọkan tọkan sin orilẹede Naijiria ninu iṣẹ ologun.

O ni Ọgagun naa ti figba kan ri jẹ agbẹnusọ fun ikọ AFN nileeṣẹ ologun nigba aye rẹ.

Bakan naa ni Ọgagun to doloogbe naa tun kopa ribi ribi ninu igbogun ti awọn agbesunmọmi ni Naijiria.

Ọgagun Samaila ni awokọṣe rere ni Ajagunfẹyinti Abubakar jẹ fun ọpọ eeyan pẹlu bi o ṣe jẹ olufọkansin nigba to ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọmogun Naijiria.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ko ṣai fidii rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọmogun mọ-ọn mọ pinnu lati ma sọ nnkankan lori akitiyan lati doola ọgagun naa ko to di pe o jade laye.

Alukoro ileeṣẹ ọmogun fikun ọrọ rẹ pe iku Ọgagunfẹyinti Abubakar ti tun fawọn ọmogun lagbara sii lati tẹsiwaju pẹlu ija tawọn n gbe koju awọn agbesunmọmi.

O ni awọn ko ni kaarẹ ninu akitiyan awọn lati daabo bo ọmọ orilẹede Naijiria.

''Ni bayii, iṣẹ si n lọ lọwọ lati fọwọ ofin mu gbogbo eeyan to wa nidii iku ọgagun Abubakar ati gbogbo awọn agbesunmọmi to n dunkoko mọ alaafia orilẹede Naijiria.

A fi n dawọn ọmọ Naijiria loju wi pe a ko ni sinmi titi ti a o fi ṣẹgun awọn agbesunmọmi ti alaafia yoo si jọba ni Naijiria,'' alukoro ileeṣẹ ologun Naijiria lo sọ bẹẹ.