Amẹ́ríkà àti Iran ń da àdó olóró bo ara wọn léraléra fún ọjọ́ méjì

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Orilẹede Iran ati Amẹrika ti n da ado oloro pada funra wọn ni agbegbe Middle East fun ọjọ meji leralera.

Igbesẹ naa si lo n mu iyemeji ba adehun jogun o sinmi ti awọn orilẹede mejeeji fọwọsi losu kẹrin ọdun yii.

Amẹrika ni awọn ado oloro ti ohun n ju lo wa lati daabo bo ara oun, ti oun si doju ija naa kọ awọn ibudo ologun ati awọn ẹrọ atọpinpin.

Saaju ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti fẹsun kan Iran pe o yin ado oloro ba ọkọ ofurufu hẹlikọpita awọn ni ẹgbẹ Strait of Hormuz, to si jẹjẹẹ lati ṣekọlu si Iran pada nitori o ṣe pataki.

Awọn awakọ ofurufu meji to wa ninu hẹlikọpita Apache ni wọn sọ pe wọn duroonu oju omi doola, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ṣe sọ fun BBC.

"Awọn awakọ ofurufu meji lo wa ninu hẹlikọpita naa, awọn mejeeji wa laaye lai farapa," Trump kọ soju opo ayelujara Truth Social rẹ.

Igba akọkọ niyi ti Amẹrika yoo padanu Apache lati igba ti oogun Amẹrika, Israel ati Iran ti bẹrẹ.

Ileeṣẹ US Central Command (Centcom) ti ṣaaju sọ pe awọn ọmọ ogun meji ni wọn ti kọkọ doola laaarin wakati meji sira wọn, ti wọn si wa ni alaafia lẹyin ti ọkọ ofurufu AH-64 ja lulẹ ni ẹba odo Oman.

Trump ninu ohun to kọ soju opo Truth rẹ sọ pe awọn ọmọ ogun ṣẹṣẹ sọ fun oun pe awọn ọmọ ogun Iran ṣekọlu si ọkọ ofurufu awọn nigba ti wọn n yi Strait of Hormuz ka.

O ni awọn ko i tii le sọ ohun to maa ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ bayii.

Ṣaaju ki Trump to sọ eyi ni ọkan lara awọn to n jiroro fun Iran, Mohammad Baqer Qalibaf fi soju opo ayelujara pe ṣiṣe idunaadura ye awọn yekeyeke amọ awọn tun le lo ilana mii.

"Ẹ yẹba lori adehun yin, a maa yipada si ohun ti a mọ ọ ṣe julọ."

Ninu atẹjade ti Centcom fi lede ni wọn ti sọ pe nnkan bii aago meje abọ ọjọ Aje ni Iran ṣekọlu si ọkọ ofurufu naa.

Wọn ni ikọ ọmọ ogun ori omi lo sare doola awọn Ologun naa.

Agbẹnusọ Centcom sọ fun BBC pe awọn ọmọ ogun Task Force 59 ti wọn fi Bahrain ṣe ibujokoo ni wọn doola awọn ọmọ ogun naa.

Iran naa fi ado oloro fesi pada fun Amẹrika lawọn ibudo ologun rẹ to wa lagbegbe Middle East

Nigba ti oun naa n da ado oloro pada, orilẹede Iran ju ọpọ ado iku naa sawọn ohun elo ologun Amẹrika to wa lawọn agbegbe yika Middle East.

Awọn ibudo ologun Amẹrika to wa ni Bahrain ati Kuwait lo gbina lati ipasẹ ado oloro Iran to n ju fun ọjọ meji lera.

Ikọ ologun Iran ni oun tun ju ado iku si aarin gbungbun ibudo ologun Amẹrika to wa ni Jordan.

Israel àti Iran bẹ̀rẹ̀ ìkọlù ọ̀tun, UK, Amẹ́ríkà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí ogun sinmi

Orilẹede Iran ati Israel ti wọn ti dawọ ogun duro lati oṣu Kẹrin ọdun yii tun ti bẹrẹ ikọlu sira wọn pada.

Eyi n waye bi awọn ilu mejeeji ṣe tun bẹrẹ si i kọlu ara wọn lẹyin oṣu meji ti wọn ti kọkọ jẹ ki ogun o mi.

Ṣaaju ni BBC ti ri awọn fidio meji kan to ṣafihan ohun to jọ ado oloro lati Iran, to mori le Israel lalẹ ana ọjọ Aiku.

Fidio kan ṣafihan ibi tawọn eeyan kan ti n wọde niluu Kermanshah, ni Iwọ-Oorun Iran.

Awọn nnkan ija meji ti wọn ju soju ọrun farahan, awọn kan si n ju asia Iran ati Hezbollah, bẹẹ ni wọn n pariwo "Allahu Akbar" lati fi han pe awọn faramọ ọn.

Bakan naa ni fidio keji tun fi awọn to faramọ ijọba han, ti wọn n ṣewọde pẹlu ohun ti wọn ju si ofurufu to n fo loke.

Iwadii fi han pe tuntun ni awọn fidio naa, ojulowo ni wọn pẹlu, ki i ṣe ofege ti wọn fi imọ ẹrọ AI ṣe.

Israel ṣalaye ikọlu si Iwọ-oorun ati Aarin-gbunbun Iran

Ninu alaye Israel lori awọn iṣẹlẹ yii, o ni oun ti kọlu ikọ ologun kan ni Iwọ-oorun ati Aarin gbungbun Iran.

"Ko ti i pẹ pupọ ti ikọ ologun Israeli kọlu awọn ologun Iran ninu ijọba wọn ni Iwọ-oorun ati Guusu Iran."

Bẹẹ ni ikọ ologun Isreale 'Israel Defense Forces', kọ ọ soju opo Telegram.

Wọn ko sọ boya awọn eeyan ku tabi farapa ninu ikọlu naa tabi ibi pato ti wọn ti ṣe ikọlu ọhun nigba naa.

Ki ni Hezbollah sọ?

Ninu ọrọ ti ikọ Hezbollah sọ loju opo Telegram ni wọn ti ni awọn ju ado oloro si awọn ọkọ ologun Isreali kan, atawọn ṣoja ni Guusu Lebanọn ni aarọ oni.

Wọn fi kun un pe ikọ ologun kan lawọn fojusọ lẹyin ilu Beit Yahoun.

Hezbolla sọ pe awọn ṣe bẹẹ lati da a pada fun Isreali to yi adehun jogun-omi pada, ti wọn kọlu awọn abule ni Guusu Lebanon.

Ikọ ologun Israeli n gbe awọn igbesẹ kan ni Guusu Lebanon, eyi ti wọn ni awọn fẹ fi dena Hezbollah ki wọn ma le ju ado oloro si Ariwa Israel ni.

Israel ko ti i sọrọ si awọn iṣẹlẹ Hezbolla yii lasiko ti a pari iroyin yii.

America ati ijọba UK rọ Israel ati Iran lati dawọ ogun duro pada kia

Aarẹ orilẹede America, Donald Trump pẹlu Olootu ijọba ilẹ United Kingdom; Keir Starmer ti pe fun didawọ ogun duro laaarin orilẹede Iran ati Israel lẹyẹ o sọka.

Ṣaaju ninu ọrọ Trump lo ti rọ Olootu ijọba Israeli, Benjamin Netanyahu, lati ma ṣe da ikọlu pada fun Iran .

" Ikọlu Iran ko pa ẹnikẹni lara, Israel naa ju tiẹ, kaluku ṣe tiẹ ni, a ko fẹ omiran mọ. "

Bẹẹ ni Aarẹ Donald Trump wi.

Bakan naa ni Olootu ijọba UK, Keir Starmer, rọ Iran ati Israel lati ṣiwọ rogbodiyan.

O ni ki won pada si adehun jogun- o-sinmi ti wọn ṣe. Starmer fi kun un pe rogbodiyan ni Middle East yii n mu idaamu wa ju, igbesẹ akin si ti bẹrẹ lorii bi alaafia ti ko lopin yoo ṣe waye.

"Rogbodiyan yii n nipa to lagbara lorii gbogbo agbaye, titi kan UK.

"Fun idi eyi, mo rọ gbogbo igun to kan, ojuṣe gbogbo wa ni lati pada si adehun jogun o sinmi, o si ṣe paraki pe ki eyi ye wa yeke."

Bẹẹ ni Keir Starmer wi.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Israel ati Iran jọ ṣe adehun lati dawọ ogun duro. Israel ni oun fọwọ si i nigba naa, ṣugbọn o ni oun ko ka Lebanon mọ ọn.

Ọjọ kẹtala oṣu Kẹrin: Ileeṣẹ ologun US bẹrẹ si i di oju opo papakọ Iran pa, lẹyin ti ọrọ ko wọ laaarin Pakistan, Washington ati Tehran.

Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹrin: Ikede jogunomi laaarin Israel ati Lebanon ti Trump kede bẹrẹ, wọn ni yoo gba ọjọ mẹwaa.

Ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹrin: Iran kede pe oju opo Strait of Hormuz – to n gbe ẹpo pupọ to wa ni titipa latọwọ Tehran lasiko ogun – ti di ṣiṣi fun idokoowo.

Eyi wa bẹẹ titi di ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin ti Tehran ni oun yoo ti oju opo naa nitori bi US ṣe n di i pa.

Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹfa oṣu Kẹfa, US ati Iran koju ara wọn ninu ikọlu.

America dojusọ awọn duroonu Iran, Iran naa si dojukó ibudo ologun America kiri.

Ọjọ keje oṣu Kẹfa ni Iran ju ado oloro kọju si Israel, eyi ti ikọ ẹlẹsin Islam to n tako wọn naa pe ni " ibẹrẹ odidi ọsẹ kan tawọn yoo fi maa ṣe ikọlu lọ".

Wakati diẹ lẹyin ti Israle kede pe oun kọlu Hezbollah ni Guusu Beirut ni Iran naa da a pada.