You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwọ́de tako àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè bẹ̀rẹ̀ ní South Africa, ọmọ Naijiria méjì kú, ìbẹ̀rùbojo gbalẹ̀ kan
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa, ijọba Naijiria si ti sọ pe wọn ko gbọdọ ṣe magomago kankan ninu iwadii ọhun.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Sanwo-Olu fẹ́ kúrò nípò gómìnà torí àìlera, ló ṣe fa ọwọ́ igbákejì rẹ̀ sókè bíi awọ tó kájú ìlù?
Nibi ipade bọnkẹlẹ kan waye nile ijọba to wa lagbegbe Marina ni Obafemi Hamzat ti kede niwaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC pe oun nifẹ lati dije fun ipo gomina.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,58
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Agbébon ṣíná ìbọn bolẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ tó ń gbá bọ́ọ̀lù lóríi pápá, 29 kú, ọ̀pọ̀ farapa
Papa iṣere ile ẹkọ alakọọbẹrẹ kan ni awọn to n gba bọọlu ti n gba a ki wọn too maa gbọ iro ibọn lakọlakọ.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹnu ṣe ń kun Funke Akindele pé ó fojú pa Pasuma rẹ́ lóde àti bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni ẹnu kun Funke Akindele lori ọrọ ikini, nigba ti Toyin Abraham ti won jọ jẹ oṣere n ki i lode Iyabo Ojo, ṣugbọn ti Funke ko dahun.
Fídíò, Ǹ jẹ́ ẹ mọ nípa Ọdún Ẹlẹ́gba Èjìwà l‘Eko níbi tí takọ-tabo kìí wọ aṣọ tàbí bàtà?, Duration 1,59
BBC News Yorùbá wà nílùú Irù ní ìpínlẹ̀ Eko, lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba Èjìwà láti mọ pàtàkì ọdún náà àti ìdí tó ṣe jẹ́ èèwọ̀ fún akọ àti abo láti wọ bàtà tàbí aṣọ lásìkò ọdún náà.
Ìdí mẹ́rin rèé táwọn ibùdó ìfọporọ̀bì Naijiria kò fi lè ṣiṣẹ́ láéláé - Obasanjo ṣàlàyé
Oloye Olusegun Obasanjo loun sọrọ yii latari nnkan ti ileeṣẹ epo rọbi Shell sọ foun lasiko toun jẹ Ààrẹ orilẹede Naijiria.
Ọ̀nà wo ni iléeṣẹ́ ológun gbà pa àgùnbánirọ̀ kan ní Abuja, tí ẹbí rẹ̀ fi fọnmú?
Awọn aworan ati fidio ti wọn fi han BBC ṣafihan bi gbogbo inu yara naa ṣe daru, ti oju ọta ibọn si wa lara ogiri ati ilẹkun inu yara naa.
"Bí ọ̀wọ́ngógó epo bàálù ṣe gbòde, àti lọ sí Hajj lọ́dún yìí di ọwọ́ Ọlọ́run àti ìjọba"
Alhaja Kaola ti wọn n pe ni Ummu-li-Muminat sọ pe awọn olujọsin ti ijọba ba ṣeranwọ owo fun nikan ni owo ti wọn ti san tẹlẹ le gbe lọ si Mecca bayii.
Kí ló fa ogun 'Wẹtiẹ' tíjọba ológun ṣe bi ìjọba alágbádá àkọ́kọ́ wó, èyí tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ àti ẹ̀kọ́ tó yẹ káwọn olóṣèlú àsìkò yìí kọ́?
BBC News Yoruba ṣe àkojọpọ itan to rọ mọ laasigbo Wẹtiẹ, idaluru to mu ọpọ ẹmi lọ nilẹ Yoruba, to si mu kawọn ologun gba ijọba, lati mu kawọn ọmọ Naijiria kẹkọọ, paapaa awọn eeyan ti ọrọ oselu gbe ru.
Wo àwọn owó àjẹmọ́nú òṣìṣẹ́ tí ìjọba àpapọ̀ ṣàfikún rẹ̀ àti ìdí tí NLC ṣe yínmú lórí àfikún náà
Ẹka to n ri si owo tawọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria n gba lo fi ikede yii lede ninu atẹjade wọn, ẹgbẹ osisẹ si fesi lori rẹ.
Seyi Makinde kò yẹ nípò gómìnà lórí ogun Wẹ́ẹ̀ti ẹ̀ tó sọ, ẹ̀yin agbófinró, ẹ má fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeré - APC yarí
Atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu APC fi lede latọwọ agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Felux Morka lọjọ Aiku fẹsun kan pe Gomina Makinde n pe fun ogun lori ẹsun ti ko ni ẹsẹ nilẹ pe iṣejọba to wa lode n gbiyanju lati sọ orilẹ ede Naijiria di ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Aiyedatiwa jẹ wá lówó oṣù mẹ́fa, ó tún fẹ́ lé wa níbi tí ìrandíran wa ń gbé láti 1943 - Àwọn àkàndá ẹ̀dá Ago Ireti figbeta l'Ondo
Yatọ si awon to ni arun ẹ̀tẹ̀ to n gbe ni Agọ ireti, awon mi-in naa n gbe nibẹ ti won ko ni arun yii ṣugbọn ti wọn ṣi jẹ akanda ti ẹya ara miran pe nija, pẹlu awọn to jẹ talika ti ko le da ọwọ mu lọ sẹnu rara.
Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ àwọn ọmọ onílùú lásìkò ìfẹ̀hónúhàn- Ìjọba Naijiria kìlọ̀ fáwon èèyàn rẹ̀ tó ń gbé ní South Africa
Ikilọ yii lo n waye lẹyin ti alakooso agba kan lati Naijiria fun Johannesburg, sọ pe iwadii fi han pe awon kan n pete iwọde tuntun lagbegbe Gauteng, laaarin ọjọ Aje si Ọjọruu oṣu yii (Monday 27 - Wednesday 29 April).
Erin kọlu ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Oyo, pa èèyàn kan, ẹlòmíì di àwátì
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede.
Fídíò, Oògùn ni àwọn darandaran kọ́kọ́ fi na ọkọ mi kí wọ́n tó ṣa wẹ́lẹwẹ̀lẹ - Ìyàwó Oloye tí darandaran pa n'Ibadan, Duration 4,29
Iyawo oloogbe sọ pe oun ati ọmọ oun sa asala fun ẹmi wọn ni awọn afurasi naa ko gbẹmi awọn naa.
Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yá $516m láti ṣe ọ̀nà láti Sokoto sí Badagry
Ọrọ naa lo wa ninu lẹta kan ti Aarẹ igbimọ aṣofin naa, Godswill Akpabio ka niwaju awọn ọmọ ile.
Ìgbẹ́jọ́ ọmogun 36 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba Tinubu bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ iléeṣẹ́ ológun Naijiria
Olu ileeṣẹ ologun Naijiria to ṣe ifilọlẹ igbẹjọ naa lonii ọjọ Ẹti ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹrin yii sọ pe ẹsun iditẹ eyi to lewu fun aabo orilẹede lẹsun ti wọn fi kan awọn ọmogun naa.
Ohun tó fàá tí Ààrẹ Kenya fi sọ pé ọmọ Naijiria ò lè sọ èdè òyìnbó dáadáa
Ọrọ yii ti bẹyin yọ tori ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria atawọn ọmọ orilẹede Afirika mii ni wọn ti bu ẹnu ẹtẹ lu Ruto wi pe o n tabuku orilẹede ilẹ Afirika mii.
Ẹ gbà wá o, àwọn agbébọn ti fẹ́ pa wá tán - Àwọn ọ̀dọ́ Gúúsù Kwara figbeta
Nibi ti ọrọ naa ka wọn lara de, awọn ọdọ Guusu Kwara ti wọn n gbe niluu Eko, Ilorin ati awọn ilu mi-in tẹ ọkọ leti wa silẹ lati dara pọ mọ ifẹhonuhan yii.
Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn OAU ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń múra ìdánwò, jáde láyé
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ọmọ ọdun mejidinlogun kan to n kẹkọọ imọ iṣẹgun nile ẹkọ kan naa, Timilehin Toromade jade laye loju orun rẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2026 yii.
Gbọin-gbọin ni a wà lẹ́yìn Makinde bí òkè, àhesọ ọ̀rọ̀ lásán n'ìròyìn tó ní a fẹ́ yọ ọ́ nípò – Ilé Aṣòfin Oyo
Adari ẹgbẹ oṣelu to pọju nile, Họnọrebu Sanjo Adedoyin, to n ṣoju ẹkun Guusu Ogbomoso lo dabaa wi pe ki ile dibo lati kede atilẹyin wọn fun Makinde.
Wo àwọn ilé tí ìjọba Eko kò fún láǹfàní láti lo iná 'Solar' láì gbàṣẹ àti ìgbésẹ̀ tó yẹ kí o gbé kí o tó ṣe é sílé rẹ
Ina Solar yii ti pọ kaakiri to bẹẹ ti wọn n lo o ni awọn igberiko kiri, ti ọpọ eeyan ko si duro de ina mọnamọna mọ.
Ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn mẹ́wàá tún ti lùgbàdì Covid-19 ní Naijiria? Ohun tí a mọ̀ rèé
Bakan naa ni awọn ẹka ilera kaakiri ipinlẹ Cross River naa ti sọ pe ko si akọsilẹ arun Corona mẹwaa lọdọ awọn.
Ìròyìn Pàtàkì
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ọkùnrin tí ọlọ́pàá ká ẹ̀yà ara èèyàn mọ́ lọ́wọ́ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé
Baba afurasri naa ti kọkọ fẹsun jiji alupupu Boxer Bajaj mẹta, ewurẹ mẹsan an, ẹrọ ilewọ Android mẹrin, epo pupa, silinda gaasi meji, atawọn nnkan mii kan an.
Èèyàn 518 ló kú nínú rògbòdìyàn ètò ìdìbò Ààrẹ Tanzania – Ìwádìí
Igba akọkọ ree ti awọn alaṣẹ yoo mẹnuba iye eeyan to ku ninu ifẹhonuhan to waye lẹyin eto idibo naa.
Tinubu yọ Mínísítà ètò ìṣúná Wale Edun nípò, fi Taiwo Oyedele rọ́pò rẹ̀
Gẹgẹ bi akọwe ijọba apapọ, George Akume, ti ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, minisita meji ni Aarẹ Tinubu yọ nipo ti o si ti rọpo wọn pẹlu.
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ọ̀gá ọlọ́pàá 167 fi ń sọ tẹnu wọn níwájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣèbáwí ọlọ́pàá? Àlàyé rèé
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Anthony Placid, lo fọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ.
Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba Tinubu ṣe lọ l'Abuja
Gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ ri, Timipre Sylva, naa wa lara awọn afurasi ọhun, ṣugbọn nnkan ti a gbọ ni pe o ni na papa bora.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Owo tí wọ́n já síhòhò l'Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
Ṣaaju ni awọn asofin ijọba ibilẹ naa ti ni ki Tope Omolayo lọ rọ ọ kun nile foṣu mẹfa gbako, latari aawọ to ni pẹlu Ọlọwọ tilu ọwọ; Ọba Ajibade Ogunoye. Awọn ti ọrọ ijanisihoho naa soju wọn salaye, pe alaga yii pada sẹnu isẹ la
Irọ́ ni pé a ti dá ẹ̀yáwó tí à ń ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró - NELFUND
Loju opo X ajọ NELFUND lo ti kede lọjọ Abamẹta to kọja, pe oun ko figba kankan gbe e jade pe oun dawọ ẹyawo duro na.
Àwọn ọlọ́pàá tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣèwọ́de l'Abuja lórí owó ìfẹ̀yìntì sísan, gbégi dínà ilé-iṣẹ́ Ààrẹ
Oniruuru iwe ilewọ ni wọn mu dani to fi mọ asia orilẹede Naijiria ati asia ileeṣẹ ọlọpaa.
Bàbá kan yìnbọn pa ọmọ rẹ̀ méje àti ọmọ ọlọ́mọ kan
Awọn ọlọpaa ibẹ ṣapejuwe ipaniyan naa bii "idaamu abele".