You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àkíyèsí nípa ààbò àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín lórí ìkànnì WhatsApp BBC Yorùbá
Níní ìfọkàntán nínú wa jẹ ohun tó ṣe pàtàkì sí wa. Èyí túmọ́ sí pé BBC ní ìfarajìn sí ríri dájú pé ààbò wà fáwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín (personal data). Ó ṣe pàtàkì fún-un yín láti kà nípa àkíyèsí yìí kí ẹ ba à le mọ̀ bí àti ìdí tí a ṣe ń gba àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ náà. Àkíyèsí yìí ṣe àpèjúwe bí a ṣe ń gba àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ yín àti bí a ṣe ń lò wọ́n nígbà àti lẹ́yìn ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú wa, ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó de ààbò àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn èèyàn.
Àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín wo ni BBC máa gbà àti báwo ni a ṣe máa lò wọ́n?
BBC máa gba àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín èyí tí ẹ ti pinnu láti fún wa nípa dídarapọ̀ àti títẹ̀lé ìkànnì wa. Àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ náà le jẹ́ lára àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí tàbí gbogbo rẹ̀
Àkọ́ọ́lẹ̀ ara ẹni
- Lára àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara ẹni tí a le ṣàmúlò ni
- Orúkọ tó wà ní ojú òpó WhatsApp yín
- Nọ́ḿbà yín
- Àwòrán tó bá wà lójú òpó yín
Àwòrán tí ẹ bá fi sí ojú òpó yín àti irú ètò ààbò tí ẹ bá ń ṣàmúlò le mú kí BBC gba àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan èyí tí ẹ fi léde fúnra yín. Àpẹẹrẹ àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni:
- Ẹ̀yà yín
- Ipò ìlera yín
- Ẹ̀sìn tàbí ohun tí ẹ gbàgbọ́ nínú rẹ̀
- Irú ìbálòpọ̀ tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí
- Ìròrí yín nípa òṣèlú
Ṣíṣe àwòrán WhatsApp yín ní ohun tí gbogbo èèyàn kò le rí
Tí ẹ bá ṣe àwòrán tó wà lójú òpó WhatsApp yín ní ohun tí gbogbo èèyàn le rí, BBC yóò ní àǹfàní láti rí èyí náà. A rọ̀ yín láti ṣe àyípadà èyí sí ohun tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tí ẹ bá ní orúkọ wọn lórí fóònù yín nìkan ni wọ́n le rí. Ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ọ̀nà láti mú àdínkù bá bí àwọn èèyàn yóò ṣe ní àǹfàní sí mímọ̀ nípa yín láti orí ìkànnì wa.
Ta ló ń ṣe àmójútó àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ yìí?
BBC nìkan ló ń ṣe àmójútó àti àkóso àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara ẹni tí a bá fi kalẹ̀ sọ́dọ̀ wa, tó sì wà lórí àwọn ẹ̀rọ BBC.
WhatsApp nìkan ló wà nídìí àkóso àti àmójútó àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara ẹni tí ẹ fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì náà. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ mọ̀ pé òfin tó de ètò ààbò àkọ́ọ́lẹ̀ ara ní WhatsApp ìyẹn WhatsApp Privacy Policy and Terms of Service wà lórí yín. WhatsApp le pín àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ yìí pẹ̀lú iléeṣẹ́ Meta.
Alákòóso kọ̀ọ̀kan ló lè pinnu nípa ohun tí wọ́n bá fẹ́ lo àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín fún àti ọ̀nà tí wọ́n máa gbà láti lò ó. Láìsí àní-àní, BBC kò ní ṣe àmúlò àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ láti fi ṣàmúlò ohun tí kò sí nínú àkíyèsí yìí, ohun tí à ń gba àkọ́ọ́lẹ̀ yín fún kò kọjá títẹ̀lé wa lórí ìkànnì BBC WhatsApp Channel lọ. Alákòóso kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ tẹ̀lé òfin tó dá ààbò bo àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn èèyàn.
Òfin tó de ṣíṣe àmúlò àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín
Àṣẹ yín láti lo àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ yín ni a gbára lé láti lò ó. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀yin lẹ pinnu láti darapọ̀ mọ́ ìkànnì wa. Tí ó bá wù yín láti má gba àwọn ìròyìn wa lórí ìkànnì yìí mọ́, ẹ ní àǹfàní láti yọ ara yín kúrò nínú ìkànnì náà nígbà tó bá wù yín.
Pínpín àkọ́ọ́lẹ̀ yín
BBC kò ní pín àkọ́ọ́lẹ̀ yín pẹ̀lú ẹnikẹ́ni láì gba àṣẹ lọ́wọ́ yín.
Níní àkọ́ọ́lẹ̀ yín lọ́wọ́
BBC yóò ṣàmúlò àkọ́ọ́lẹ̀ yín láwọn àsìkò tó bá yẹ láti ṣe àmúṣẹ àwọn kókó tó wà nínú àkíyèsí yìí.
Àwọn ẹ̀tọ́ yín àti ìròyìn míì
Ẹ ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin tó de àkọ́ọ́lẹ̀ ara ẹni ti UK. Ẹ lè bèèrè fún àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ ara yín tí BBC fi pamọ́ nípa yín tó fi mọ́ BBC Account data àti àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tí a ti ṣàpèjúwe ṣáájú sókè níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì ni lọ́wọ́.
Ẹ lè kàn sí wa lórí email dataprotection.officer@bbc.co.uk. Tí ẹ bá ní ìbéèrè tàbí tó wù yín láti mọ̀ nípa ẹ̀tọ́ yín ní kíkún, ẹ jọ̀wọ́ ẹ kàn sí BBC's Privacy and Cookies Policy lórí ìkànnì ayélujára
Tí a bá ní ohun kan tó ń kan yín lóminú lórí bí BBC ṣe ṣàmúlò àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ yín, ẹ lè fi tó àwọn aláṣẹ tó ń ṣe àmójútó tó wà ní UK ìyẹn the Information Commissioner's Office (ICO) létí lórí
Ṣíṣe àyípadà àkíyèsí yìí lóòrè kóòrè
A máa ṣe àgbéyẹ̀wò àkíyèsí nígbà tí àyípadà kan gbòógì kan bá wà lórí lílo àkọ́ọ́lẹ̀ yín.