You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni pé Sunday Igboho ló ṣe bí wọ́n ṣe gba ìtúsílẹ̀ àbúrò Adelabu àtàwọn ọmọ rẹ̀? Ohun tí a mọ̀ rèé
Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ẹni to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation ti ni ohun ko lọwọ ninu bi wọn ṣe gba itusilẹ awọn ẹbi Minisita tẹlẹ ri fọrọ ina mọnamọna, Adebayo Adelabu, tawọn ajinigbe ji gbe laaarin ọsẹ to lọ yii.
Ni alẹ ọjọ Abamẹta ni fidio kan jade sori ayelujara to ṣafihan bawọn ẹṣọ aabo ṣe gba itusilẹ aburo minisita naa atawọn ọmọ rẹ meji lẹyin ti wọn ti lo ọjọ mẹta ni ahamọ awọn ajinigbe.
Amọ ni ọjọ Aiku ni iroyin kan n lọ lọri ayelujara pe Sunday igboho lo lọ gba itusilẹ awọn eeyan naa kuro ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
Amọ Sunday Igboho ti wa jade sita pe oun ko lọwọ ninu bi awọn eeyan naa ṣe kuro ni ahamọ awọn ajinigbe ati pe iroyin ofege ni awọn kan n gbe kiri lori ayelujara.
Igboho fifi ori aṣeyọri naa sọ oun jẹ tita abuku awọn ẹṣọ aabo ti wọn ṣiṣẹ takuntakun lati gba itusilẹ awọn eeyan naa, ti wọn si mu meji balẹ ninu awọn ajinigbe naa.
Afọmọ ti Igboho ṣe yii lo n waye lẹyin ti sọrọsọrọ ori amohunmaworan kan, Rufai Oseni gbe soju opo X rẹ pe Sunday Igboho lo mọ bi wọn ṣe gba itusilẹ ẹbi Adebayo naa.
Mi ò lọ́wọ́ nínú ìjínigbé Aburo Adelabu - Sharafadeen Alli figbe ta
Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nibi eto idibo ọdun 2027, Sẹnetọ Sharafadeen Alli ti ni oun ko lọwọ ninu bi wọn ṣe ji aburo Minisita tẹlẹ ri fọrọ ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu atawọn ibeji rẹ gbe.
Ninu atẹjade kan ti Alli fi lede lọjọ Aiku lo ti jiyan ẹsun naa.
Ẹ o ranti pe ni alẹ ọjọ Abamẹta ni wọn gba itusilẹ aburo Adelabu atawọn ibeji rẹ ninu ile kan ni ilu Ibadan lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ji wọn gbe lasiko ti wọn n lọ sile ẹkọ.
Lẹyin ti awọn eeyan naa gba itusilẹ ni awọn kan n gbe iroyin pe oludije sipo gomina lo wa nidii bi wọn se ji wọn gbe.
Ṣugbọn Sharafadeen Alli ninu atẹjade to fi sita ti jiyan ẹsun naa, to si rọ awọn ẹṣọ aabo lati tuṣu de isalẹ koko lori ijinigbe naa.
O wa rọ awọn eeyan lati ma tẹti si iroyin to gbode naa, bo ṣe ni irọ to jina sio ootọ ni.
Bakan naa lo rọ awọn ẹṣọ aabo lati ṣẹwadii awọn to gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa rẹ.
Àbúrò mínísítà iná mọ̀nàmọ́ná tẹ́lẹ̀, Adebayo Adelabu àti ìbejì rẹ̀ tí ajínigbé gbé lọ n'Ibadan ti gba ìtúsílẹ̀- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ti kede pe oun ti gba Abilekọ Olaide Busayo Adegoke John-Paul to jẹ aburo fun minisita ina mọnamọna tẹlẹ; Adebayo Adelabu, pẹlu awọn ọmọ rẹ ibeji ọkunrin; Peter ati Paul kuro ni akata awọn ajinigbe.
Alẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹfa oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fidi eyi mulẹ, ninu atẹjade ti Alukoro apapọ; DCP Anthony Okon Placid, fi sita l'Abuja.
Atẹjade naa sọ pe alaafia ni obinrin naa ati awọn ọmọ rẹ wa.
O ni ṣugbọn awọn ọlọpaa fibọn mu meji balẹ ninu awọn ajinigbe naa lasiko ti wọn koju wọn.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni awọn ajinigbe kan gbe obinrin naa pẹlu awọn ibeji rẹ ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejila.
Ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo ni won ti gbe wọn ni nnkan bii aago meje aabọ owurọ, lasiko ti aburo Adelabu n ko awon ọmọ rẹ lọ sile ẹkọ.
Bawo ni ọlọpaa ṣe ri wọn gba silẹ lẹyin ọjọ mẹta?
Gẹgẹ bi alaye Alukoro ọlọpaa ilẹ Naijiria, Anthony Placid, o ni ifọwọsowọpọ ikọ ọtẹlẹmuyẹ 'Force Intelligence Department Intelligence Response Team (FID-IRT) lo mu aṣẹyọri naa wa, ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ Satide naa.
Placid ṣalaye pe itọpinpin, ifimufinlẹ ati iṣẹ ọpọlọ gidi ni ikọ agbofinro to kapa awọn ajinigbe naa lo ti wọn fi tọpasẹ irin awọn ajinigbe ọhun, eyi to pada ja si kikoju ara ẹni pẹlu ikọ FID-IRT.
"Lasiko idojukọ naa, afurasi ajinigbe meji pade iku wọn, a si gba ibọn meji lọwọ wọn.
"A gba awọn to wa nigbekun naa kalẹ lai farapa, wọn si ti wa nibi ifọkanbalẹ bayii, wọn n gba itọju ati aduroti."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ṣalaye.
Atẹjade naa fi kun un pe awọn ọlọpaa ti fi kun ipa wọn lati ri I pe wọn mu awọn to sa lọ ninu ikọ ajinigbe naa.
Iwadii wọn bi wọn ṣe wi, fi han pe awọn kan fara gba ọta ibọn ninu awọn to sa lọ naa, pẹlu rẹ ni wọn fi ara ṣoko.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa sọ pe iṣẹ n lọ lati tọpasẹ awọn to sa lọ naa, ki wọn si mu wọn ṣinkun lati koju ofin.
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria dupẹ lọwọ araalu fun aduroti wọn lasiko iṣẹlẹ naa, wọn ṣeleri pe awọn ko ni I yẹ ninu idaabobo ẹmi ati dukia araalu, gẹgẹ bi iṣẹ tawọn gbe dani.
Agbébọn jí àbúrò mínísítà fún ohun àmúṣagbára tẹ́lẹ̀, Adebayo Adelabu àti ìbejì rẹ̀ gbé lọ ní Ibadan: ohun tí a mọ̀ rèé
Awọn agbebon ji Aburo minisita fun Ina monamona tẹlẹri ati ọmọ rẹ meji lọ nilu Ibadan
Awọn afurasi agbebọn ti ji aburo obinrin minisita fun ina mọnamọna tẹlẹ, Bayo Adelabu ati awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ ibeji gbe lọ lagbegbe Elewura, Challenge, niluu Ibadan.
Isẹlẹ naa lo waye ni nnkan bii aago meje aabọ arọ oni ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2026.
A gbọ pe akoko ti Olaide Busayo Adegoke John-Paul atawọn ibeji rẹ, Peter ati Paul nclọ si ile ẹkọ wọn ni isẹlẹ ijinigbe ọhun waye.
Inu ọkọ ayọkẹlẹ Hundai pupa kan ni awọn eeyan naa wa ninu rẹ ki wọn to ji wọn gbe gẹgẹ biee fọran kan to ti n milẹ titi lori ayelujara bayii ti akọroyin BBC Yoruba ri.
"Aburo mi n palẹmọ lati lọ ba ọkọ rẹ niluu Amerika"
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin, Femi Awogboro to jẹ agbenusọ fun Oloye Bayo Adelabu ṣalaye pe lootọ ni awọn agbebọn ji aburo oloṣelu naa lọ toun ti awọn ibeji rẹ.
Atẹjade naa tẹnumo wi pe, inu ibanuje ọkan ni Adelabu ati gbogbo idilẹ wọn wa bayii lẹyin iṣẹlẹ naa.
Idile naa tẹnumọ wi pe awọn ni igbagbọ ninu iṣẹ awọn agbofinro lati ri daju wi pe awọn ti wọn ji gbe ri ominira gba laipẹ.
Arabinrin John-Paul lo ti fi igba kan ri jẹ oṣiṣẹ ile ifowopamo kan ko to kọwe fi ipo naa silẹ to si n gbaradi lati lọ pade ọkọ rẹ to wa ni Amẹrika.
Idile ọhun wa rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin to le ran awọn ọlọpaa lọwọ lori ibi ti awọn agbebọn naa gbe arabinrin John-Paul ati awọn ọmọ rẹ mejeji si lati fi to awọn ẹṣọ alaabo leti.
A ti bẹrẹ iwadii - Ọlọpaa
Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka ninu atẹjade to fi lede, fidi iṣẹlẹ naa mule.
Ayanlade ṣalaye wi pe ni kete ti ọlọpaa ipinlẹ Oyo gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti ran eka ọtẹlẹmuyẹ wọn lati bẹrẹ si n fi imu finlẹ lori ijinigbe ọhun.
Ọlọpaa wa rọ awọn to ba ni iroyin to le ran wọn lọwọ lati yọju ki wọn si sọ ohun ti oju wọn ri.
ileeṣẹ naa rọ awọn olugbe ipinlẹ Oyo lati fi ọkan balẹ nitori ọlọpa yoo sa gbogbo ipa rẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn.