Kí ló ṣe Adewale Eleso, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó fi ṣiṣẹ́ abẹ, ipò wo sì ni ìlera rẹ̀ wà?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọpọ awọn ti wọn ri gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu nni, Adewale Adeoye, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Adewale Ẹlẹṣọ, lọsẹ to kọja yii, lo n ṣe kayeefi.
Nibi eto isinku gbajumọ oṣere nni, Taiwo Hassan tawọn eeyan tun n pe ni Ogogo, ẹni to jade laye lọjọ Aiku to lọ lọhun, ni wọn ti ri Adewale Elesho.
Ko si nnkan meji to n jẹ ki awọn eeyan maa beere ibeere nipa ohun to ṣe agba alawada naa, bi ko ṣe ti egbo nla kan to yọ sibi oju rẹ.
Kete ti awọn eeyan to wa nibi eto isinku naa ti ri Eleso, ni ẹru ti n ba wọn pe, ko ma jẹ pe jẹjẹrẹ ti ẹya ara, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'skin cancer' lo ṣe ọkunrin naa ni kokoro naa fi duro soju rẹ.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe aisan jẹjẹrẹ lo ṣeku pa Ogogo, ẹni ti wọn sinku rẹ lọjọ Aje, ọsẹ to kọja.
Àríyànjiyàn tó ti wáyé lórí ọ̀rọ̀ egbò Elesho
Oniruuru ariyanjiyan lo si ti jẹyọ nipa egbo nla to wa loju Elesho lori ayelujara laaarin ọsẹ to kọja yii, koda titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe egbo lasan ni, bẹẹ lawọn miran n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ aisan jẹjẹrẹ agọ ara to maa n ba awọn Afin finra lo ṣe ọkunrin naa.
Latigba naa ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii gbadura fun un pe, ohunkohun ti egbo naa yoo ba jẹ, ki Ọlọrun da ẹmi rẹ si, koun na ma si fi ọjọ ọlọjọ lọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni nnkan bi oṣu kan si asiko ti a wa yii,Temitope Osoba ati Ogogo ni aisan jẹjẹrẹ ran lọ sọrun alakeji lagboole tiata.
Eyi gan lo n ba awọn eeyan lẹru wi pe ki adẹdaa lọọra ẹmi Eleso, ẹni ti awọn eeyan ṣi n gbadun rẹ titi di asiko yii, nipa awọn ere awada rẹ.

Oríṣun àwòrán, Olufemi Adejonwo/Facebook
Elesho ti ṣiṣẹ́ abẹ
Ṣugbọn ninu atẹjade ti agbẹnusọ agba fun ẹgbẹ oṣere ANTP, eyi tii ṣe Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners ti Elesho wa ninu rẹ, Ọmọọba Adejonwo Oluwafemi fi sita, o ni Eleso ti ṣiṣẹ abẹ tori egbo oju rẹ naa.
Oluwafemi sọ ninu atẹjade to fi soju opo Facebook rẹ lọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja, o ni Elesho ti ṣiṣẹ abẹ, ara rẹ si ti n balẹ.
"Nipa oore ọfẹ Ọlọrun, iṣẹ abẹ naa lọ daadaa. Oun funra rẹ n ṣe daadaa, o si n dahun si itọju," Ọmọọba Adejonwo sọ bẹẹ.
O wa dupẹ lọwọ awọn ololufẹ agba adẹrinpoṣonu naa fun pipe, adura, atẹjiṣẹ ati ifẹ ti wọn fi han si Eleso lasiko ipenija yii.
"Gbogbo yin la dupẹ lọwọ rẹ fun pipe, adura ati ifẹ ti ẹ fi han. A dupẹ gidigidi."
Bakan naa lo rawọ ẹbẹ pe ki awọn eeyan tubọ maa gbadura alaafia fun Elesho, ki ara rẹ le tete ya.



























