Wo iye ìgbà tí Ààrẹ Bola Tinubu ti béèrè fún ẹ̀yáwó lágbàáyé

Aare Tinubu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kọwe sile igibmọ aṣofin agba Naijiria, lati ṣagbeyẹwo ẹyawo tuntun ti ijọba apapọ fẹẹ ya.

Owo ti ko din ni ogun biliọnu ($20.52bn) dọla ati biliọnu kan aabọ (€1.05bn ) pọun ni Aarẹ Tinubu loun fẹẹ ya lorukọ Naijiria.

Ninu lẹta ti Aarẹ kọ sile igbimọ aṣofin agba, eyi ti Aarẹ wọn, Godswill Akpabio ka si awọn ọmọ igbimọ naa leti, lo ṣalaye nipa awọn ohun ti ijọba fẹẹ fi owo naa ṣe.

Oṣu Kẹfa si Oṣu Keje Ọdun 2023

Ninu oṣu Kẹfa si oṣu Keje ọdun 2023, Aarẹ Bola Tinubu kọwe sile igbimọ aṣofin lati ya ẹgbẹrin miliọnu owo dọla, lati fi ṣiṣẹ lori ohun ti yoo mu idẹrun ba gbogbo ọmọ Naijiria.

Aarẹ sọ pe eyi pọn dandan nitori bi wọn ṣe yọ owo irnwọ ori epo, iyẹn sọbsidi, ati lati pese owo fun awọn idile to ku diẹ kaato fun.

Iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari lo ti kọkọ beere fun ẹyawo ọhun tẹlẹ, ko too di pe ijọba naa kogba wọle.

Oṣu Kọkanla, ọdun 2024

Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2024, Aarẹ Tinubu tun beere fun ẹyawo owo to le diẹ ni biliọnu meji ($2.2b) dọla, lati fi ṣe awọn iṣẹ akanṣe to lo pọn dandan lati ṣe

Aarẹ sọ nigba naa pe owo yii yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, yoo si tun mu adinku ba iye owo ti ijọba maa n na lori yiya owo ku, bakan naa ni yoo ro afipamọ Naijiria nita lagbara.

Ko pẹ rara ti ile igbimọ aṣofin agba fi buwọ lu eto ẹyawo ọhun.

Lẹyin eyi, ni ijọba Naijiria tun n sọrọ lori yiya idaji miliọnu owo dọla lati banki agbaye lati fi koju iṣoro to n koju ẹka eto ẹkọ.

Oṣu Kẹfa si Oṣu Kẹjọ, ọdun 2025

Inu oṣu Karun-un, ọdun 2025 ni Aarẹ Bola Tinubu gbe iwe lọ siwaju ile igbimọ aṣofin agba Naijiria lati buwọlu eto ẹyawo tijọba fẹẹ ya.

Miliọnu mọkanlelogun aabọ ($21b) dọla; biliọnu mẹẹdogun owo Yẹn (¥15b) tilẹ Japan, ati miliọnu marundinlaadọrin (€65m) Yuro ni awọn owo ti Aarẹ loun fẹẹ ya.

Ninu lẹta ti Aarẹ kọ sile igbimọ aṣofin, lo ti ṣe atupalẹ awọn ohun ti ijọba fẹẹ fi owo naa ṣe.

Awọn ohun miran ti Aarẹ sọ pe wọn yoo tun na owo yii le lori ni idagbasoke iṣẹ akanṣe, iṣẹ agbẹ, eto ilera, eto ẹkọ, ipese omi, idagbasoke, eto aabo, to fi mọ ipese iṣẹ fawọn araalu, ati awọn miran.

Ṣaaju asiko yii, ninu oṣu Kejila, ọdun 2024, ni Aarẹ Tinubu sọrọ nipa awọn gbese owo to n ya , to si ni kii ṣe lati fi pa ọmọ Naijiria lara, bi ko ṣe lati fi mu idagbasoke ba iṣẹ akanṣe.

Oṣu Kẹta, ọdun 2026

Ninu oṣu yii ni ile igbimọ aṣofin buwọ lu biliọnu mẹfa owo dọla ($6b) ti Aarẹ Tinubu gbe iwe rẹ lọ fun wọn lati ṣagbeyẹwo rẹ.

Owo yii ni ijọba Naijiria ya biliọnu marun-un dọla ($5b) nile ifowopamọ First Abu Dhabi lorileede Saudi Arabia.

Aarẹ sọ pe oun beere fun ẹyawo yii, ni ibamu pẹlu ipin kinni labala kọkanlelogun ati ipin kinni labala kẹtadinlọgbọn ninu iwe ofin gbese, iyẹn ebt Management Office Establishment Act, ti ọdun 2003.

Biliọnu kan ($1b) dọla yooku ni ijọba ya nile ifowopamọ Citibank, eyi ti wọn fẹẹ na lori atunṣe Lagos Port Complex ati Tin Can Island Port.

Ṣé lóòótọ́ ni Ààrẹ Tinubu fẹ́ẹ́ yá $20.52b owó dọ́là?

Aarẹ Tinubu lasiko to n buwọlu iwe kan gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti gbe iwe aba lati ya owo tuntun lọ siwaju ile igbimọ aṣofin agba ilẹ Naijiria, to si n bẹbẹ pe ki wọn buwọ lu owo to fẹẹ ya naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, owo yii ni aarẹ sọ pe yoo ṣe iranwọ fun awọn iṣẹ akanṣe idagbasoke to n lọ kaakiri orileede naa.

Owo ti ko din ni ogun biliọnu ($20.52bn) dọla ati biliọnu kan aabọ (€1.05bn ) pọun ni Aarẹ Tinubu loun fẹẹ ya lorukọ Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio lo ka lẹta ti Aarẹ Tinubu kọ fun awọn aṣofin nibi ijokoo ipade wọn to waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

Ninu lẹta naa, Aarẹ Tinubu rọ awọn aṣofin lati buwọlu eto ẹyawo naa, pẹlu bo ṣe sọ pe owo ọhun yoo ṣe iranlọwọ pupọ fun awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke, eto ilera, eto ẹkọ, ipese omi, eto aabo, iṣẹ, to fi mọ abojuto eto iṣuna.

Aarẹ sọ pe owo ti wọn fẹẹ lọ ya nita yii ṣe pataki lati di alafo kudiẹ-kudiẹ to wa laarin awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ilu to n lọ lọwọ.

"Mo n fi akọsilẹ eto ẹyawo ijọba apapọ ti ọdun 2026 si 2027 ranṣẹ, fun ile igbimọ aṣofin lati foju aanu wo o, ki wọn si buwọlu, lati le jẹ ki awọn akanṣe iṣẹ lọ siwaju," Tinubu kọ ọ bẹẹ.

Aarẹ ṣalaye pe akanṣe iṣẹ ati eto to wa ninu alakalẹ eto ti wọn fẹẹ fowo naa ṣe, ni wọn ti wo finnifinni, pẹlu afikun pe yoo kopa to jọju ninu eto idagbasoke awujọ.

O ni agbekalẹ naa tun wa lati pese iṣẹ, mu ilọsiwaju ba iṣẹ ọgbọn atinuda, okoowo ara ẹni, adinku ba iṣẹ ati oṣi, to fi mọ riro aabo ounjẹ lagbara.

"Agbekalẹ yii lo wa lati da iṣẹ silẹ, mu iṣẹ ọgbọn atinuda dagbasoke, ṣe iranwọ fun okoowo, mu adinku ba iṣẹ ati oṣi, ati riro aabo ounjẹ lagbara, ti gbogbo eyi si mu idagbasoke ba igbe aye ọmọ Naijiria," o sọ bẹẹ.

Níbo ni àwọn iṣẹ́ àkànṣe ti ń lọ lọ́wọ́?

Aarẹ Tinubu ninu lẹta to kọ ranṣẹ naa lo ti sọ pe kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorileede Naijiria, to fi mọ FCT tii ṣe olu ilu Naijiria ni wọn ti lo owo naa fun iṣẹ idagbasoke.

O ni ipele ti iṣẹ akanṣe idagbasoke Naijiria de duro bayii, nilo iranwọ owo, to si jẹ ko di mimọ pe afi ki awọn bọ sita lati ya owo, lati di alafo to ṣi silẹ lati pari awọn iṣẹ naa.

"Ni ibamu pẹlu agbekalẹ eto iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ lorileede yii, ati pẹlu eto iṣuna ti a nilo lati di alafo naa, o ti ṣe dandan fun wa lati jade sita lọ ya owo ti a nilo," Tinubu sọ bẹẹ.

O ni awọn iṣẹ to ti de ipele abojuto gidi ni wọn yoo kọkọ dari owo naa si, paapaa julọ ẹka eto ina mọnamọna, eto irinna ati ilera.

Aarẹ wa rọ awọn alakoso ile igbimọ aṣofin ati gbogbo ile naa lati buwọlu erongba lati ya owo naa, to si jẹ ko di mimọ pe bi wọn ba tete buwọlu, ni yoo jẹ ki awọn iṣẹ akanṣe naa ya.

Ǹjẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti buwọ́lu lẹ́tà náà?

Ṣugbọn ṣa, ile igbimọ aṣofin agba ni lati ṣagbeyẹwo lẹta naa daadaa, paapaa lori awọn eto ẹyawo to ti wa nilẹ tẹlẹ, ati ọna agbekalẹ eto ẹyawo tuntun.

Nigba to n sọrọ lori lẹta naa, Aarẹ ile igbimọ ọhun, Godswill Akpabio sọ pe eto eyawo ti farahan ninu awọn eto ẹyawo tẹlẹ ati agbekalẹ eto iṣuna, bo tilẹ pe o sọrọ lori igba ti owo ti wọn ya tẹlẹ yoo ṣiṣẹ de.

"Agbekalẹ eto ẹyawo naa wa ninu lẹta yii, ṣugbọn sibẹ, o wa ninu eto ẹyawo ti a buwọ lu tẹlẹ, ati pe eto ẹyawo lati ita la buwọ lati ọdun 2025 si 2027, titi de 2028," Akpabio sọ bẹẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn yoo gbe iwe tuntun yii fun igbimọ ile igbimọ aṣofin lori ẹyawo oke-oku fun agbeyẹwo, to si lo ṣee ṣe ki wọn buwọlu.