Lẹ́yìn-o-rẹ̀yìn, orúkọ Oriyomi Hamzat bá orúkọ àwọn olùdíje sípò gómìnà Oyo INEC tuntun jáde

Oriyomi Hamzat wọ aṣọ olomi aro, o de fila, wọ igo oju, o n wo ọọkan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lori ẹni to jẹ ojulowo oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu Accord ni ipinlẹ Oyo, ajọ to n mojuto eto idibo Naijiria, INEC ti kede orukọ Oriyomi Hamzat gẹgẹ bi ojulowo oludije.

Orukọ Oriyomi Hamzat lo ba orukọ awọn oludije tuntun ti INEC gbe sita lọjọ Kọkanla, oṣu Kẹwaa, jade eyi to n fidi rẹ mulẹ pe oun ni oludije fun ẹgbẹ naa ti INEC fidi rẹ mulẹ.

Eyi tumọ si pe Oriyomi Hamzat ni orukọ rẹ wa lọdọ INEC ti yoo si kopa nibi eto idibo sipo gomina ti yoo waye ni ọjọ Kẹfa, oṣu Keji ọdun 2027.

Ẹ o ranti pe lati oṣu Karun-un ọdun 2026 ni ifanfa ti n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Accord lori ẹni to jẹ ojulowo oludije wọn gangan.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe igun meji lo ṣeto idibo abẹnu lati yan oludije sipo gomina nigba naa.

Igun akọkọ to je eyi tawọn alaṣẹ ẹgbẹ naa gba wọle lati oke sọ pe Oriyomi Hamzat nikan ni oludije to gba fọọmu lati dije dupo gomina, to si da fọọmu naa pada lasiko to yẹ.

Igun naa sọ pe Olakunle Busari ti ọpọ mọ si Gudugudu ati Fatai Owoseni ti awọn naa ra fọọmu lati dije ko tete ko awọn iwe ẹri wọn kalẹ lasiko ti wọn la kalẹ, ti wọn si wọgile orukọ wọn.

Igun keji ni tirẹ eyi ti ikọ alaṣẹ Accord ni ipinlẹ Oyo n ṣatilẹyin fun sọ pe Gudugudu lo jawe olubori nibi eto idibo abẹnu ti wọn ṣe, pe Hamzat kii ṣe oludije ti ko ni alatako.

Amọ Oriyomi Hamzat ni igbimọ alaṣẹ pada fun ni iwe ẹri gẹgẹ bi oludije eyi to mu ki Gudugudu gba ile ẹjọ lati pe igbesẹ naa nija.

Gudugudu ni ki ile ẹjọ da INEC duro lati ma gbe orukọ Hamzat gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ Accord nitori ko kopa nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ.

Lẹyin o rẹyin, INEC ti wa gbe orukọ Hamzat jade bayii gẹgẹ bi oludije sipo gomina Oyo lẹgbẹ oṣelu Accord, ti wọn si yọ orukọ Gudugudu.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si Gudugudu ni owurọ ọjọ Aje lati mọ iha to kọ si orukọ ti INEC gbe jade, o ni oun ko ṣetan lati sọ ohunkohun lori rẹ.

O ni ti asiko ba to oun gan-an ni oun maa jade sita sọrọ funra oun.

Mi o mọ idi ti INEC fi yọ orukọ amọ gbogbo rẹ maa niyanju laipẹ - Adebutu

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu Peopels Democratic Party, PDP Oladipupo Adebutu ti rọ awọn alatilẹyin rẹ lati ṣe suuru, ki wọn si ma fa wahala kankan bi ajọ INEC ko ṣe fi orukọ rẹ sara awọn oludije sipo gomina nibi orukọ ti wọn gbe jade lọjọ Aiku.

Adebutu ni ẹru ko bao do oun nitori gbogbo awọn iwe ẹri to yẹ ni oun fi kalẹ lọdọ ajọ INEC, eyi to fidi rẹ mulẹ pe ojulowo oludije ni oun.

O ni laaarin asiko ti INEC fun awọn oludije lati fi orukọ ranṣẹ lori ẹrọ ayelujara ni oun ṣe, ti oun ko si mọ idi ti wọn fi yọ orukọ oun lara awọn oludije.

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP naa tun sọ pe yatọ si pe oun fi gbogbo akọọlẹ to yẹ silẹ fun INEC, o ni awọn oṣiṣẹ ati aṣoju ajọ naa wa nibi eto idibo abẹnu ti wọn ti yan oun gẹge bi oludije, ti idi ti orukọ oun fi di awati ruju pupọ.

O wa kọminu lori bi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC tẹka ipinlẹ Ogun ṣe n ko INEC ni papa mọra to fi di pe orukọ oun jẹ yiyọ kuro amọ ti orukọ awọn oludije sile aṣofin wa nibẹ.

Adebutu tun parọwa sawọn alatilẹyin rẹ lati fọkan balẹ pe o maa niyanju laipẹ.

Ni ipinlẹ Kwara ẹwẹ, ajọ INEC sọ pe awọn yọ orukọ oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC, Duwatsu Musa nitori ọjọ ori.

INEC ni Musa ko i tii le pe ẹni ọdun marundinlogoji ti ofin la kalẹ gẹgẹ bi ọjọ ori to kere julọ ki eeyan to le dupo gomina ni Naijiria.

Àjọ INEC fi orúkọ àwọn olùdíje sípò òṣèlú ọdún 2027 síta

Lara awọn oludije sipo oṣelu

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti gbe ẹkunrẹrẹ orukọ awọn oludije sipo oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027 sita.

Ninu ẹkunrẹrẹ orukọ ti INEC fi sita, ni wọn ti yọ awọn oludije ẹgbẹ oṣelu kọọkan kaakiri ipinlẹ to wa ni Naijiria.

Ipinlẹ Ogun, Gomba, Kano ati ipinlẹ mẹtalelogun miran ni ajọ INEC ti yọ orukọ awọn oludije to ṣe pataki nibẹ.

Latigba ti INEC ti kede awọn orukọ wọnyi, ni oniruuru awuyewuye ati ariyanjiyan ti n jẹyọ, pẹlu bi awọn oludije ati ẹgbẹ oṣelu ṣe n fẹsun kan ẹgbẹ APC pe wọn lọwọ ninu igbesẹ INEC.

Lara awọn oludije ti INEC yọ orukọ wọn ni minister feto ikansira-ẹni tẹlẹ, Isa Pantami; Ladi Adebutu ti ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ogun; to fi mọ Aminu Gwarzo, oludije lẹgbẹ oṣelu NDC, ati awọn miran.

Nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun n fẹsun kan APC wi pe awọn lo wa nidi bi INEC ṣe yọ orukọ Ladi Adebutu, awọn ọmọ ẹyin Pantami n sọ fawọn eeyan wọn pe ki wọn lọ fọkanbalẹ, nitori pe awọn yoo bori.

Kete ti INEC ti fi orukọ awọn oludije wọnyi sita ni awọn ọmọ ẹyin wọn ti n fo faye pe oriire nla ni, ati pe aṣeyọri ibo ti n daju.

Lara awọn oludije sipo aarẹ ti INEC fi orukọ wọn sita ni Aarẹ Bola Tinubu to jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu APC; Atiku Abubakar, oludije lẹgbẹ oṣelu ADC; Peter Obi, oludije lẹgbẹ oṣelu NDC; Omoyele Sowore, oludije lẹgbẹ oṣelu AAC, ati Seyi Makinde, toun n dije lẹgbẹ oṣelu APM.

Awọn oludije miran ti INEC kede ni wọn wa lati awọn ipinlẹ mẹrindinlọgbọn bii: Abia, Adamawa, Akwa Ibom, Bauchi, Benue, Borno, Cross River, Ebonyi, Enugu, Gombe, Jigawa, Kaduna, ati Kano.

Awọn yooku ni: Katsina, Kebbi, Kwara, Lagos, Nasarawa, Ogun, Oyo, Plateau, Sokoto, Taraba, Yobe, Rivers ati Zamfara.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìpínlẹ̀ àti orúkọ tí INEC gbé jáde

Ipinlẹ Abia

Opah Eric Chinemeucheya - APC

Kalu Kalu Agwu - ADC

Ijioma Uchechukwu Charles - APGA

Otti Alex Chioma - LP

Ogah Iroetugo Ndubuisi - NDC

Anosike Kelechi - PDP

Ipinlẹ Adamawa

Modibo Hammantukur Ribadu - ADC

Umaru Babangida Bajabure - ADP

Amini Ahmed Galadima - APC

Ishaku Elisha Cliff - LP

Dahiru Aishatu Ahmed - NDC

Vunobolki Maurice Michael - PDP

Ipinlẹ Akwa Ibom

John James Akpanudohedehe - ADC

Eno Umoh Bassey - APC

Jimmy Stella Monday - APGA

Mbaba Michael Bush - LP

Enyong Michael Okon - NDC

Brownson Ibanga Akpan - PDP

Ipinlẹ Bauchi

Halliru Dauda Jika -ADC

Shehu Jinda Yunusa - ADP

Abubakar Mohammed Abdullahi - APC

Aliyu Idris Muhammed - LP

Kashim Ibrahim Muhammed - NDC

Adamu Usman Ahmed - PDP

Ipinlẹ Benue

Hembe Iowase Herman - ADC

Nyimba Kwaghshir - ADP

Alia Hycinth Iormem - APC

Byuwan Mathias Terwase - LP

Shija Terhemba - NDC

Aondoakaa Michael Kaase - PDP

Ipinlẹ Borno

Babagana Buhari - ADC

Munguno Rufai Alhaji - ADP

Gubio Alhaji Mustapha - APC

Konto Umar - LP

Ibrahim Sanusi Kashim - NDC

Abba-Gana Ibrahim Baba - PDP

Ipinlẹ Cross River

Otu Bassey Edet - APC

Obu Ogar Osim - LP

Archibong Arthur Javis - PDP

Joelyn Ita Hogan - Bassey - ADP

Ipinlẹ Delta

Ogboru Ovedje Great - ADC

Oborevwori Sheriff - APC

James Esther - LP

Itovwaye Chris - NDC

Mrakpor Peter - PDP

Obuseh Felix Ogechukwu - SDP

Ipinlẹ Ebonyi State

Ukpai Mbah Udeh - ADC

Nwifuru Ogbonna Francis - APC

Nwodom Lucy Chinwe - APGA

Eze Oko Spledour - LP

Igwe Nwagu Palinus - NDC

Chukwuma Odii Ifeanyi - PDP

Ipinlẹ Enugu

Ocho Bodoeze Chukwuma - ADC

Mbah Peter Ndubuisi - APC

Ugwu Okwudilichukwu Chukwudera - LP

Ohaa Chiyeaka Christian - NDC

Nnaji Uchechukwu Geoffrey - PDP

Iloka Friday - SDP

Ipinlẹ Gombe

Bala Bello - ADC

Adeh Nuhu Milah - ADP

Gwamna Jamil Isyaku - APC

Muazu Zubairu Halilu - LP

Ardo Babayo Kumo - NDC

Ipinlẹ Jigawa

Sabo Mohammed Nakudu - ADC

Sulaiman Ibrahim - ADP

Namadi Umar - APC

Abdul'aziz Aminu - LP

Dutse Aminu Sani - NDC

Sule Mustapha Lamido - PDP

Ipinlẹ Kano

Ibrahim Ali Amin - ADC

Muhammed Abdullahi - ADP

Yusuf Abba Kabir - APC

Santuraki Hamisu - LP

Abacha Muhammed Sani - PDP

Hussaini Bello Ado - SDP

Ipinlẹ Katsina

Ahmed Baba Kaita - ADC

Ahmed Murtala - ADP

Umar Dikko Radda - APC

Ilu-Barde Aliyu - NDC

Gard Yakubu Lardo - PDP

Ipinlẹ Kwara

Zakari Muhammed - ADC

Adeshina Ajisafe - ADP

Yakubu Danladi Salihu - APC

Abdulmunin Yinka Ajia - NDC

Kawu Suleman Bolakale - PDP

Amokanye David Adetoyese - NNPP

Ipinlẹ Kebbi

Malami Abubakar - ADC

Yahaya Ayuba - ADP

Idris Nasir - APC

Usman Aliyu - LP

Umar Faruk - SDP

Ipinlẹ Niger

Mohammed Kpataugi - ADC

Mohammed Umaru Bago - APC

Mohammed Adamu - APGA

Mohammed Usman - LP

Muhammed Yahaya Adam - NDC

Muhammed Mamman Nami - PDP

Ipinlẹ Eko

Gbadebo Rhodes Vivour - ADC

Hamzat Kadri Obafemi - APC

Odunaike Oluwapemilerin Olurotimi - LP

Doherty Olufunsho Adeshina - NDC

Doherty Adedeji Olugbemiga - PDP

Olaniyi Olufemi - SDP

Ipinlẹ Ogun

Lawal Jimi Adebisi - ADC

Anifowose Johncrownfit Kayode - ADP

Adeola Solomon Olamilekan - APC

Ola Williams Adeyinka - SDP

Ipinlẹ Rivers

Pidomson Gabriel Baritulem - ADC

Kingsley Ogundu Chinda - APC

Boms Chima Ernest - LP

Lulu-Briggs Dumo Owukori - NDC

Ejekwu Samuel Soni - PDP

Ben-Gurion Peter - SDP

Ipinlẹ Nasarawa

Nuhu Angbazo- ADC

Christopher Mamman - ADP

Aliyu Ahmed Wadada - APC

Gaza Jonathan Gbefwi - LP

Emmanuel David Ombugado - PDP

Muhammed Abubakar Adamu - SDP

Ipinlẹ Oyo

Adegoke Taofeek Adeboyega - ADC

Alli Sharafadeen Abiodun - APC

Salami Gbolagade Tajudeen - APGA

Kareem Thompson Sola - LP

Yusuf Akim Adebola - NDC

Gbolarumi Hazeem Ola – PDP

Ipinlẹ Plateau

Sura John Sunday - ADC

Dawop Sani Sai'du - ADP

Muftwang Caleb Manasseh - APC

Nura Tanko - LP

Ropshik Kefas Wungak - PDP

Ipinlẹ Sokoto

Manir Muhammad Dan'iya - ADC

Sarkin Larabawa Nasiru - ADP

Aliyu Ahmed Sokoto - APC

Haliru Abubakar Dikko - LP

Aliyu Shamsudeen Ahmad - NDC

Abdullahi Sokoto Abubakar - PDP

Ipinlẹ Taraba

Abubakar Umar Tutare - ADC

Mamman Abubakar Mustapha - ADP

Kefas Agbu - APC

Shiddi Danjuma Usman - APGA

Nathan Sanda - LP

Yahaya Mohammed Sani - NDC

Bwacha Emmanuel - PDP

Ipinlẹ Yobe

Kassim Gaidam - ADC

Mohammed Nasiru Saleh - ADP

Wali Baba Mallam - APC

Kolomi Aji - LP

Ibrahim Mallam Shuaibu - NDC

Usman Abdullahi - PDP

Ipinlẹ Zamfara

Aliyu Bashir - APGA

Yusuf Sani - LP

Marafa Kabiru Garba - NDC

Shehu Gusau Ibrahim - PDP

Musa Hamza - SDP