Kí ló dé tí ẹnu fi ń kun Sisi Alagbo lórí ayélujára àti ọ̀rọ̀ tó sọ lórí rẹ̀?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ obinrin to n ta agbo lori ayelujara, Eniola Fagbemi, ti ọpọ mọ si Sisi Alagbo, ti sọrọ aforijin lọwọ awọn olofẹ rẹ lẹyin ti fidio ibalopọ rẹ lu sita lori ayelujara.

Ninu fidio naa ni ohun ati ọkọ rẹ Adesola Hakeem ti n ba obinrin mii lajọṣepọ, ti oun naa si wa lori ibusun pẹlu wọn ni ihooho.

Ọjọ Aje ọsẹ yi ni fidio naa kọkọ fa ori ayelujara ya, eyii ti ọpọ araalu ti bu ẹnu atẹ lu u.

Fagbemi sọ nipa nnkan to n dojukọ lẹyin ti fidio ọhun lu sita, o ni iṣẹlẹ naa ti gba orun loju oun fun ọpọ ọjọ, koda oun lo oogun orun amọ awọn oogun naa ko ṣiṣẹ.

Nigba to n sọrọ loju opo Facebook rẹ, o ni "Mo gba pe mo ti ṣe aṣisẹ, mo si tọrọ aforinjin pẹlu gbogbo ọkan mi lori fidio to n mi ori ayekujara titi.

"Mo tọrọ aforin lọwọ gbogbo awọn ti mo ja kulọ.

"Asiko yii jẹ asiko to lagbara fun mi, mo si bẹbẹ fun aforinjin lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹmi, ẹ jọọ ẹ jẹ ka kuro lori ọrọ yii nitori ori ayelujara naa ni mo ti n ri atilẹyin to n fun mi lounjẹ. Ẹ jọọ ẹ ma sọrọ abuku si mi nitori mo n la ọpọ nnkan kọja lọwọ yii."

Sisi Alagbo tẹsiwaju pe "Mi o le jẹun, bẹẹ ni mi o le sun fun ọpọ ọjọ, koda oogun orun ti mo lo ko ṣiṣẹ fun mi mọ. Ẹ jọọ ẹ darijin mi gbogbo Eniyan.

"Ẹ jọọ ẹ darijin mi, mi o fẹ ṣe ara mi leṣe, okun kekere ti mo ni ree."

Taa ni Sisi Alagbo?

Fagbemi 'Sisi Alagbo' di gbajumọ ori ayulujara lẹyin to bẹrẹ si n ta agbo loju opo Facebok rẹ.

O sọ lasiko naa pe iṣẹ iya-iya oun ni iṣẹ agbo ṣiṣẹ ati tita, oun si n ta agbo kaakiri Naijiria ati titi de orilẹede China ati Qatar.

Okiki rẹ tunbọ kan si lasiko to pade agbabọọlu Super Eagles, Victor Osimhen lorilẹede Morocco lasiko idije 2025 Africa Cup of Nations.

Ninu fidio rẹ pẹlu Osimhen, o ṣafihan bo ṣe kunlẹ fun, fidio ọhun si mi ori alujara titi.

Ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ lọdun 2023, o ni bo tilẹ jẹ pe oun n ta agbo, oun kii mu ọti.

O ni ọmọlẹyin Kristi loun lọdun naa lọhun amọ Musulumi ni ọkọ ti oun fẹ.

Sisi Alagbo sọ siwaju si "Atapata dide ọmọ alagbo lasan ni mi, mo gba Ọlọrun gbọ, mo gba Jesu Krisiti gbọ, mo si gba ẹmi mimọ gbọ."

O sọ lọdun naa lọhun pe agbo oun wa fun awọn obinrin to n wo oju Ọlọrun fun ọmọ, to fi mọ agbo to n fun ọkunrin lagbara ninu iyẹwu.