Ìwọ́de tako àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè bẹ̀rẹ̀ ní South Africa, ọmọ Naijiria méjì kú, ìbẹ̀rùbojo gbalẹ̀ kan

Awọn to n ṣe ifẹhonuhan tako awọn alejo ni South Afrika

Oríṣun àwòrán, Thuthuka Zondi/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan ọpọ awọn ọmọ ilẹ okeere to wa ni South Africa ko balẹ mọ bayii lẹyin ti awọm ọmọ orilẹede naa bẹrẹ si n gbogun ti awọn alejo.

Lọwọ yii, ọmọ Naijiria meji lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti a gbọ pe awọn ọmọ orileede South Africa kọlu wọn.

Aṣoju ijọba Naijiria si South Africa, Okey-Uche fidi rẹ mulẹ pe, ọmọ Naijiria meji, Amaramiro Emmanuel ati Ekpenyong Andrew padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọtọtọ nibẹ.

Awọn mejeeji ku lẹyin ti awọn oṣiṣẹ South African National Defence Force lu wọn niluu bara logunjọ oṣu Kẹrin ti a wa yii.

O ni wọn mu Andrew lẹyin wahala kan pẹlu awọn ọlọpaa Tshwane lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹrin ki wọn to pada ṣawari oku rẹ nile igbokupamọsi Pretoria Central Mortuary.

Iku awọn ọmọ Naijiria naa waye lasiko ti awọn ọmọ South Africa fẹ le awọn ọmọ ilẹ okere kuro nilẹ wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa, ijọba Naijiria si ti sọ pe wọn ko gbọdọ ṣe magomago kankan ninu iwadii ọhun.

O ni "A rọ ijọba South Africa ki wọn ṣe iwadii kikun lori ọrọ yii ki wọn si fi imu gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ danrin.

"Ko si eyikeyi ẹsun ti wọn ba fi kan awọn ọmọ Naijiria naa, o ni ilana ti wọn n gbe irufẹ nnkan bẹẹ labẹ ofin.

"Afurasi kankan ko tii jẹbi ẹsun ti wọn ba fi kan an lai tii kọkọ gbe lọ sile ẹjọ. Ẹnikẹni ko gbọdọ fi ofin sọwọ ara rẹ."

Aṣoju ijọba Naijiria ọhun sọ pe oun ti bẹre ijiroro pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan ninu ijọba orilẹede naa, ati pe oun yoo pese iranlowọ to yẹ fun mọlẹbi awọn to jade laye.

Okey-Uche wa parọwa si gbogbo awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni South Africa ki wọn fi ọkan wọn balẹ ki wọn si maa tẹle ofin orilẹede naa bi iwadii ṣe n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Iku awọn ọmọ Naijiria naa lo waye lasiko ti awọn ọmọ South Africa n gbiyanju lati le gbogbo ọmọ ilẹ okere kuro nilẹ wọn, ninu eyii ti awọn ọmọ Naijiria wa.

Ifẹhonuhan bẹrẹ ni South Africa lati le awọn ọmọ ilẹ mii kuro nilẹ wọn

Awọn to n ṣe ifẹhonuhan tako awọn alejo ni South Afrika

Oríṣun àwòrán, Thuthuka Zondi/BBC

Wayi o, awọn ọmọ orilẹede South Africa labẹ asia ẹgbẹ 'March and March Movement' ti bẹrẹ iwọde niluu Pretoria, South Africa.

Awọn eeyan naa ko igi lọwọ pẹlu awọn patako ti wọn kọ oniruru akọle si lara.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ eredi ifẹhouhan wọn naa bayii amọ pẹlu awọn akole ọwọ wọn, o jọ bii pe niṣe ni wọn n sọ pe awọn ko fẹ awọn alejọ mọ nilẹ awọn.

Ẹsẹ wo ni awọn ọmọ ilẹ okeere ṣẹ awọn ọmọ South Africa?

Lara ẹsun ti wọn fi n kan awọn ọmọ ilẹ okeere naa latẹyinwa ni pe awọn lo n ta oogun oloro fun awọn eeyan wọn ti awọn oogun oloro naa si n ba aye awọn ọdọ wọn jẹ.

Nigba mii ẹwẹ, wọn ti fẹsun kan awọn eeyan lati orilẹede mii ni Afrika pe awọn lo n gba gbogbo iṣẹ to yẹ ki awon maa ṣe.

Wọn ni ko tọ ki awọn ajoji maa ṣiṣẹ ki wọn si maa gbe lawon ile ti dara ki awọn ọmọ onilu funra wọn ma ri iṣẹ gidi ṣe.

Koda, wọn tun n fi ẹsun kan awọn ọmọ ilẹ okere kan, bii awọn ọmọ Naijiria, pe awọn lo n gba awọn obinrin wọn ti wọn ko si jẹ ki awọn ri obinrin gidi fẹ.