Àlàyé rèé lórí bí ọdún Hijra ṣe bẹ̀rẹ̀ àti àsìkò tó bẹ̀rẹ̀

Ọkunrin meji ti wọn de fila funfun n wo oju patako to wa lara ogiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan lo ti n beere wi pe ta gan an lo bẹrẹ ọdun Hijira to jẹ ibẹrẹ ọdun tuntun fawọn musulumi jake jado agbaye.

Aafin Sultan ilu Sokoto, Sa'ad Abubakar Kẹta, to jẹ olori ẹsin Islam ni Naijiria lo kede ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹfa yii gẹgẹ bi ibẹrẹ ọdun tuntun awọn musulumi.

Ọdun Hijira bẹrẹ ni 1448 lẹyin ti Anabi Muhammad (PBUH) rinrin ajo lati Mecca lọ si Medina.

Orilẹede Saudi Arabia naa kede ọjọ Iṣẹgun gẹgẹ bii ọjọ akọkọ ninu ọdun Hijira.

Awọn ijọba ipinlẹ kan ni Naijiria tiẹ kede ọjọ Iṣẹgun yii kan naa gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun ayajọ ọdun Hijira.

Amọ, ọpọ eeyan ni wọn fẹ mọ igba tawọn musulumi bẹrẹ si ni lo kalẹnda Hijira fun igba akọkọ.

Onimọ nipa ẹsin Islam to fi ilu Abuja ṣe ibugbe, Sheikh Hussaini Zakariyya, sọ pe awọn musulumi lo kalẹnda Hijira fun igba akọkọ lasiko ijọba Caliph Umar ibn Khattab.

Sheikh Zakariyya ṣalaye wi pe oṣu nikan ni wọn maa n ka tẹlẹ ki wọn to bẹrẹ sii ka ọdun Hijira.

O ni bi wọn ṣe n ka oṣu niyii fun ọpọlọpọ ọdun titi di igba ti Umar gba lẹta lati ọdọ gomina Basra, Abu Musa al-Ash'ari, ẹni to kọminu pe o nira lati maa ka ọjọ ati oṣu.

Zakariyya ni eyi lo mu ki Caliph Umar ṣe agbekalẹ igbimọ kan lati ṣewadii lori igba ti ọdun Hijira maa n bẹrẹ gan an.

''Awọn musulumi ko tii maa tẹle ọdun Hijira ṣaaju asiko Sayyidina Umar lasiko ti ẹsin Islam ti tan kalẹ kaakiri agbaye.

Awọn kan tun kọminu wi pe ko han kedere sawọn igba tawọn iṣẹlẹ yii waye, ati pe o yẹ kawọn musulumi ni akoko ti ọdun yoo maa bẹrẹ,'' Zakariyya.

Hijrah: Kí ni pàtàkì ọdún tuntun yìí fún àwọn mùsùlùmí

Ọdun Hijrah jẹ ọdun kan to ṣe pataki pupọ fun awọn musulumi jakejado agbaye.

Awọn ipinlẹ kan loriẹede Naijiria ti kede isinmi lẹnu iṣẹ lati fun awọn Musulumi lanfani lati ṣe ajọyọ ajọ naa de gongo.

Hijirah ọdun yii jẹ wiwọ ọdun 1446 fun awọn Musulumi.

Iyatọ to wa laarin ọdun musulumi ati ọdun yooku ni pe wọn ko kii ṣe e papọ pẹlu awọn yooku ati pe orukọ wọn yatọ.

Aworan awọn musulumi to n gba adura

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni awọn Gomina ti kesi awọn araalu lati lo asiko ajọyọ fi gba adura fun ifọwọsowọpọ ati igbagbe alaafia fun orilẹede Naijiria.

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ninu atẹjade kan ti olubadamọran rẹ, Sulaiman Olarenwaju rẹ buwọlu fun awọn akọroyin rọ gbogbo musulumi lati ma gba adura fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Ki ni a n pe ni Ọdun Musulumi ati pe ki ni pataki rẹ

Ọdun Hijirah ti wa ṣaaju ki wọn to Anọbi Muhammad (SAW) ṣugbọn wọn ko lo awọn oṣu lasiko naa.

Lilo awọn oṣu ninu ọdun musulumi bẹrẹ lẹyin ti Anọbi gbera kuro lati ilu Mecca lọ Medina lorilẹede Saudi Arabia.

Idi ree ti wọn fi pe ọdun to pari 1445 AH (AH tumọ si ọdun 1445 lẹyin ti Anọbi rin irinajo).

Oṣupa wiwo ni ẹṣin Islam fi n wo asiko, ko si nkankan ninu awọn oṣu musulumi ti ọjọ rẹ pe bii ti ọdun Gregorian.

Awọn musulumi maa n ṣe ajọyọ irinajo Anọbi Muhammad (PBUH) lati Makkah lọ Medina.

O ṣe koko fun awọn musulumi nitori o n jẹ ki wọn ní oye sii nípa Ibẹrẹ ẹṣin Islam ati bi o ṣe di ọkan gboogi.

Lọjọ kini oṣu Muharram, awọn ko ni ọjọ kan fun ijọsin ṣugbọn o duro gẹgẹ asiko lati ranti irinajo Anọbi ati ilakọja rẹ.

Gbogbo Musulumi ni wọn ma n rọ lati gba awẹ ati adura lọjọ kini ọdun.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa oṣu Muharram

Oṣu Muharram ni oṣu akọkọ, ti wọn si tun ma pe ni oṣu Al Hijiri

Iye ọjọ to wa ninu oṣu yii maa n yi si ara wọn. Nigba miran o le jẹ Ọjọ mọkandinlọgbọn, o si tun le jẹ ọgbọn ọjọ ni yoo wa ninu oṣu yii.

Awọn Musulumi gbọdọ gba awẹ lọjọ kẹsan an ati ikẹwaa oṣu yii ti wọn n pe ni Tashua ati Ashurah.

Oṣu yii kọ awọn Musulumi ni igboya ati jija fun idajọ òdodo.

Oṣu Ewọ ni oṣu Al Muharram ti awọn musulumi yoo si yago fun ayẹyẹ lati le ṣe apọnle fun Imam Hussain.