Kíni ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ túmọ̀ sí fún ADC? Àlàyé rèé

Asia ẹgbẹ oṣelu ADC

Oríṣun àwòrán, ADC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria to da ikọ alaṣẹ David Mark atawọn eeyan rẹ pada gẹgẹ bi alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC farajọ bi ijawe olubori fawọn eeyan naa.

Amọ ti a ba ṣe agbeyẹwo idajọ naa daadaa, o jọ pe ifanfa to n waye lori awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ko i tii wa sopin.

Bi o tilẹ jẹ pe ile ẹjọ to ga julọ gbe idajọ ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun kọkọ da ti si ẹgbẹ kan, ile ẹjọ naa ko dajọ lori ifanfa to n waye lori ta ni ojulowo awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu ADC.

Awọn adajọ ẹlẹni marun-un ile ẹjọ to ga julọ eyi ti Adajọ Mohammed Lawal Garba dari rẹ ni gbogbo wọn fẹnuko pe idari ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe kalẹ ko tọna bi wọn ṣe paṣẹ lẹyin ti wọn da ẹjọ kotẹmilọrun to wa niwaju wọn nu.

Ohun ti idajọ naa tumọ si ni pe ile ẹjọ naa fi aaye gba lara ohun ti David Mark n beere fun ninu ẹjọ to pe, to si ni ki wọn pada si ile ẹjọ lati lọ gbọ ejọ lori ta ni ojulowo adari egbe wọn.

Ni kukuru, ohun ti eyi tumọ si ni pe fidiẹ ni ikọ David Mark yoo jẹ titi ti ile ẹjọ giga fi maa da ẹjọ wọn.

Pẹlu bi wọn ṣe jawe olubori ni ile ẹjọ to ga julọ yii, bi igun ọtọọtọ ṣe wa ninu egbẹ naa jẹ ohun to le mu idunkoko ba iduroire egbẹ oṣelu naa. Igbẹjọ to n lọ lọwọ nile ẹjọ le ṣokunfa ki aṣẹ tabi igbesẹ tawọn adari to wa nibẹ bayii ma pada fẹsẹ mulẹ paapaa ti ile ẹjọ giga to n gbọ ẹjọ wọn b ani wọn ko yẹ nipo naa.

Igbẹjọ yii n mu ikurẹtẹ ba iṣọkan ẹgbẹ naa ni iru asiko tie to oṣelu n le ni Naijiria lọwọ yii.

Gbedeke INEC lori iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun mii to tun ṣe Pataki, to si jẹ gbọnjẹgbọnjẹ ni bi ajọ to n ri si eto idibo Naijiria, Independent National Electoral Commission, INEC ṣe ti fi gbedeke ọjọ tawọn egbẹ oṣelu gbọdọ fi orukọ gbogbo ọmọ egbẹ wọn ranṣẹ si ajọ naa si ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un.

Bi o ṣe ku ọjọ diẹ ki gbedeke naa wa sopin ni ADC ṣi wa lẹnu igbẹjọ ti ifanfa to n waye lori ta ni ojulowo adari ẹgbe naa le ṣokunfa aini igbagbọ ninu orukọ ti wọn ba fi ranṣẹ, to si jẹ pe igun ọtọọtọ le forukọ ọtọọtọ ranṣẹ si INEC.

Amọ ni bayii, idajọ ile ẹjọ to ga julọ ti gbe agbara wọ igun David Mark, ni eyi to dabi ifọkanbalẹ fun igba diẹ

Titi di igba ti idajọ yoo waye lori awọn adari egbẹ ADC, ti wọn si maa yanju gbogbo aawọ to n ba ẹgbẹ naa finra, ipo ẹlẹgẹ ni ẹgbe oṣelu naa wa lori igbẹjọ ti wọn ko i tii mọ ibi to maa jasi ati gbedeke eto oṣelu.

Ni kukuru ede, bi o tilẹ jẹ pe ADC ti jawe olubori ọkan ninu awọn ipenija ti wọn n koju, ipenija awọn adari egbẹ ati iduroire rẹ ṣi n lọ lọwọ.