Sola Sobowale àti Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ lórí àmì ẹ̀yẹ AMVCA tí wọn gbà

Àkọlé fídíò, Sola Sobowale àti Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ lórí àmì ẹ̀yẹ AMVCA tí wọn gbà
Sola Sobowale àti Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ lórí àmì ẹ̀yẹ AMVCA tí wọn gbà
Published

Ni ọjọ alẹ ọjọ Satide, ọjọ Kẹsan-an osu Karun ọdun 2026 ni eto ifami ẹyẹ danilola ọlọdun ti ileesẹ agbohunsafẹfẹ Africa Magic maa n se agbatẹru rẹ waye.

Orukọ ami ẹyẹ ọlọdun naa ni wọn pe ni AMVCA, eyi to wa fawọn eekanlu lagbo tiata.

Ọpọ awọn ilumọka osere tiata lo peju sibi ami ẹyẹ naa lati awọn orilẹede to wa nilẹ Afirika.

Lara awọn gbajumọ osere to peju sibi ami ẹyẹ ọdun yii ni Osas Ighodaro, Sola Sobowale, Kanayo O Kanayo, Lateef Adedimeji, Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Adebimpe Oyebade, Bukunmi Adeaga Ilori ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa, se ni asọ n pe asọ ransẹ nibi ayẹyẹ ifamiẹyẹ da ni lọla naa, ti ọpọ awọn gbajumọ osere si wọ awọn asọ awodamiẹnu.

Sola Sobowale wọ asọ kaba gbagẹrẹ alawọ funfun, o duro siwaju ẹrọ amohunbugbẹmu, awọn eeyan kan to yi ka

"Ti eeyan ba tun n tun aye wa, isẹ tiata ni maa tun yan ni aayo, idi rẹ ni maa tun pada si"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ nibi ayẹyẹ ifamiẹyẹ da nilola naa, Sola Sobowale to gba ami ẹyẹ agba osere dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore ọfẹ to fun.

"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, o ti pẹ ti mo ti n se isẹ yii, lati aye alalumọlẹ.

Gbogbo ohun ti mo ba sọ lẹnu isẹ naa ni awọn aye n ba mi gba.

Mo tun lọ tọju ọmọ, nigba ti mo si de, se ni wọn tun gba mi pada.

Mo mọ pe ti eeyan ba tun n tun aye wa, isẹ tiata ni maa tun yan ni aayo, idi rẹ ni maa tun pada si."

Lateef Adedimeji wọ kootu oloyinbo alawọ aro, o wọ shaati funfun si abẹ rẹ, o si de tai alawọ arọ bakan naa

Ninu ọrọ soki ti Lateef Adedimeji ba BBC News Yoruba sọ, o ni ẹkọ nla kan ni oun kọ ninu sinima Lisabi, to mu ki oun gba ami ẹyẹ.

"Ẹkọ ti mo kọ ninu fiimu ti mo se, Lisabi ni pe ki onikaluku wa ja fun ominira ara wa.

Bakan naa lo yẹ ka fa ara wa mọra lati daabo bo ara wa."