Àwọn ọmogun ọlọ̀tẹ̀ pa mínísítà ètò ààbò ní Mali àti ẹbí rẹ̀ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọmogun ọlọtẹ ti ṣekupa minisita eto aabo lorilẹede Mali, Sadio Camara, nile rẹ to wa ni olu ilu orilẹede naa, Bamako.
Ọpọ ileeṣẹ iroyin lo sọ pe iṣekupani ọhun waye lasiko ikọlu awọn ọmogun ọlọtẹ to n pe fun iyapa kuro lara orilẹede naa atawọn alakatakiti ẹsin.
Ileeṣẹ iroyin ijọba fidi rẹ mulẹ pe Camara ku lẹyin to farapa lasiko ti wọn ṣe ikọlu si i nile rẹ.
Awọn ọmogun ni lati gbe Ọga agba ologun, Assimi Goita, salọ si ibikan ti ẹnikẹni ko mọ lẹyin ti wọn ṣekọlu si ile tiẹ naa.
Ajọ Azawad Liberation Front (FLA) sọ pe awọn ajagunta Russia ti ileeṣẹ ologun Mali n lo ti kede pe awọn yoo kuro ni Mali lẹyin ti wọn ti ja fun ọjọ meji.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn agbesunmọmi to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ al-Qaeda, IS ati FLA ti n ṣọṣẹ ni Mali.
Ẹbi minisita eto aabo ati ileeṣẹ iroyin France sọ pe, awọn janduku agbẹbọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu al-Quaeda tun ṣekupa awọn mọlẹbi Camara mẹta ninu ikọlu ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja ni Kita.
''Minisita eto aabo doju ija kọ ija kọ awọn ọmogun ọlọtẹ, amọ, o farapa lasiko ti wọn yinbọn sira wọn''
Agbẹnusọ ijọba Mali, Issa Ousmane Coulibaly, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lana ọjọ Aiku wi pe ọkọ kan ti ado oloro wa ninu rẹ lawọn ọmogun ọlọtẹ wa kọlu ile Camara eyi to ṣokunfa iku rẹ.
Coulibaly sọ pe minisita eto aabo doju ija kọ ija kọ awọn ọmogun ọlọtẹ naa, amọ, o farapa lasiko ti wọn yinbọn sira wọn.
O ni ile iwosan ni Camara pada ku si latari ifarapa to ni ninu ikọlu tawọn ọmogun ọlọtẹ ṣe si i.
Ikọlu naa lo jẹ ki ile Camara wo lulẹ, bakan naa lawọn ọmogun ọlọtẹ tun ba mọṣalaaṣi kan to wa lẹgbẹẹ ile Camara jẹ nibi ti wọn ti ṣekupa awọn olujọsin kan.
Oriṣiiriṣii ikọlu waye lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja ni ibudo ologun to wa lẹgbẹẹ olu ilu Mali ni Gao ati Kidal to fi mọ awọn ilu to wa laarin gbungbun orilẹede naa bii Sevare ati Mopti.
Iroyin sọ pe awọn ọmogun ọlọtẹ to n pe fun iyapa ẹya Tuareg lara Mali n ṣekọlu sawọn ilu to wa lẹkun ariwa Mali nigba ti ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM) n ṣekọlu kaakiri orilẹede naa.
Ìjà tuntun ṣẹ́yọ ní Mali, láàárín ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àti ìjọba ológun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Rogbodiyan to buyọ lọjọ Abamẹta lorilẹde Mali, ti awọn agbesunmọmi ti kọlu ibudo ologun ko ti i fi gbogbo ara relẹ tan.
Iroyin sọ pe lonii ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni wahala mi-in tun ṣẹyọ laaarin awọn ọmọ ogun ọlọtẹ atawọn ologun Mali.
Gẹgẹ bi akọroyin Mali kan ṣe ṣalaye fun BBC, rogbodiyan tuntun naa n waye ni Ariwa Kidal.
Ikọ ologun ilẹ Russia ni iroyin sọ pe wọn n ti awọn ologun Mali lẹyin lati koju awon agbesunmọmi Tuareg.
Ko dẹrun lati de Ariwa Mali lasiko yii latari ikọlu, bakan naa si ni iroyin sọ pe ikọlu ti waye ni ilu Kati, ti ko jinna si Bamako ti i ṣe olu ilu Mali.
Ikọlu tuntun yii lo n waye lẹyin ti ọjọ Abamẹta ti a gbọ pe ẹgbẹ alakatakiti al-Qaeda- lo wa nidii rẹ, pẹlu awọn ọmọ ogun alatako Tuareg lati igun Azawad Liberation Front, tabi FLA.
Adehun ti wa pe ki Russia jawọ
Agbẹnusọ FLA, Mohamed Ramdane, sọ pe adehun ti wa pe ki ilẹ Russia jawọ ninu ọrọ yii.
O pẹ ti wọn ti n ṣatilẹyin fun ijọba ologun Mali lati koju awọn agbesunmọmi ni apa Ariwa Mali.
Lọjọ to ti pẹ ni agbegbe Kidal yii ti di aaye ti ọpọ eeyan ka si ibudo agbara awon agbesunmọmi, ko too di pe awọn ologun Mali gba a pada loṣu Kọkanla ọdun 2023 pẹlu atelẹyin ẹgbẹ Wagner lati Russia .
Eyi ni wọn si fi gba ibi ti awon alatako ijọba naa ti n dari ju bii ọdun mẹwaa lọ lọwọ wọn.
Bakan naa ni FLA sọ pe oun ti rọwọ mu ni ẹkun Ariwa Gao, amọ BBC ko ti I fidi eyi mulẹ.
O ti le lọdun mẹwaa bayii ti Mali ti n koju awọn ọmọ ogun ọlọtẹ ati awọn agbesunmọmi.
Ìbúgbàmù àdó olóró tó wáyé níbùdó àwọn ológun ní Mali, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, SSOUF SANOGO/AFP VIA GETTY IMAGES
Iro ibugbamu ado oloro lo gbalẹ kan ni olu ilu Mali ti I ṣe Bamako laaarọ kutu ọjọ Satide oni ti I ṣe ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026.
Agbegbe kan ti ko jinna si ibudo awon ologun ilẹ Mali ti won n pe ni Kati ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Gẹgẹ bi awon olugbe agbegbe naa ṣe ṣalaye fun ẹka iroyi Reuters, wọn ni awon ologun ti wa kaakiri agbegbe Mali.
Won si di awon ona to wọ ibudo naa pa.
Tẹ o ba gbagbe, orilẹeda Mali naa ti n koju idaamu awon alakatakiti ẹsin ti won n pe ni jihadi lati bii ọdun mẹwaa sẹyin
Ikọ ologun to gbajọba ni 2021 nibẹ si ṣeleri pe oun yoo da alaafia pada, oun yoo si le awon alakatakiti agbesunmọmi naa lọ.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, awon olugbe Bamako so pe alaafia ko ti jọba, BBC News Yoruba yoo maa mu wa bo ba ṣe n lọ.
Awọn wo lo wa nidii ikọlu yii?
Ohun ti olugbe agbegbe naa kan ṣalaye ni pe awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam ti a mọ si JNIM, to jẹ ẹka al-Qaeda- to n ṣọṣẹ ni Mali lo wa nidii ikọlu yii.
O ni won ti kọlu awọn ẹka ologun Mali kan ri, eyi kọ ni igba akọkọ.
Fun ọpọ oṣu sẹyin ni awon ikọ JNIM ti n dọdẹ awon agba epo to n wọ Mali, eyi to n mu epo wọn gogo lorilẹede naa, paapaa ni olu ilu rẹ ti i ṣe Bamako.
Awon ibi kan ti fararọ, iro ibọn ṣi n ro gbamu lawọn ibomi-in
Gẹgẹ bi awon olugbe agbegbe papakọ ofurufu Modibo Keita International Airport, ṣe ṣalaye, wọn ni awon ibi kan ti n fararọ, amọ awon ibi kan ṣi wa ti alaafia ko ti I jọba nibẹ rara.
Olugbe kan sọ fun BBC pe "O jọ pe wọn ti n kapa ẹ ni Bamako, ṣugbọn nitosi papakọ ofurufu, iro ibọn ṣi n ro lakọlakọ, o si kan awon eeyan to n gbe lagbegbe ibudo ologun naa."
Ki ni ileeṣẹ ologun Mali sọ?
Gẹgẹ bi atẹjade ti won fi sita lọjọ Abamẹta ṣe wi, ileeṣẹ ologun Mali sọ pe awọn agbesunmọmi kan ti awon ko ti I mọ, ti dọdẹ awọn agbege kan ati bareke ologun ilẹ Mali pẹlu awon ibomiran ni Bamako.
Won fi kun un pe ija n tẹsiwaju, ati pe ikọ ologun Mali ti n da a pada fun awon agbesunmomi naa.
Wọn rọ awon araalu lati ṣe suuru ki won si jokoo jẹẹ, ki won maa fi oju ṣọri pẹlu.
Olugbe Mali kan sọ fun BBC pe gbogbo irinajo ofurufu ni won fagile laaaro Satide naa, ki ikọlu ma lọ kan papakọ ofurufu ati awon arinrinajo.
America bu ẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Mali
Ninu atẹjade kan ti ẹka to n ri si ọrọ ilẹ Africa l'America fi sita laaarọ ọjọ Satide yii ni won ti koro oju si ikọlu to waye lorilẹede Mali.
Wọn si tun ṣeleri lati ṣeranwọ fun awon ibi ti iṣẹlẹ naa fọwọ ba.
" Orilẹede America koro oju gidi si ikọlu awon agbesunmọmi to waye ni Mali.
" A ba awon to kan kẹdun pẹlu ẹbi wọn, a si duro gbọin lẹyin awon eeyan Mali ati ijọba rẹ ninu rogbodiyan yii."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade America ka.
Ṣaaju ni ẹka ileeṣẹ arinrinajo lati Mali lọ si America ti rọ awon ọmọ America to wa ni Mali, lati wa aaye aabo funra won bi ibugbami ọjọ Satide naa ṣe n waye.
Won ni ki won ma ṣe rin ni bebe awon ibi ti wahala ti n ṣẹlẹ ni Mali naa.
Ajọṣepọ Washington ati America ti kẹnu bọ epo laipẹ latari awon iditẹgbajọba to waye ni Mali, Burkina Faso ati Niger laaarin ọdun 2020 si 2023.
Ijọba America to n ṣakoso nigba naa so ajọṣepọ pẹlu awon orilẹede naa rọ, pẹlu Mohamed Bazoum ti ilẹ Niger ti won fi si ahamọ nile rẹ latigba to ti kuro nipo olori.

























